Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo mu awọn ọmọkunrin mẹta yii, Nathaniel Jacob; ẹni ọdun mẹrinlelogun, Isah Danladi; ẹni ọdun mejilelogun ati Abubakar Rabiu; ẹni ọdun mẹtalelogun. Wọn ni ikọ ajinigbe ni wọn, ati pe oju ọna marosẹ Eko s’Ibadan ni wọn ti n ṣoro wọn.
Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin yii, lọwọ ba wọn lagbegbe Fidiwọ, loju ọna marosẹ naa. Awọn ọlọdẹ kan lo ta awọn ọlọpaa lolobo nigba ti wọn ri awọn mẹta yii, ti wọn n ṣeto bi wọn yoo ṣe bọ si titi ti wọn yoo bẹrẹ iṣẹ laabi wọn.
Eyi lawọn ọlọpaa fi ko ikọ fijilante So-Safe atawọn ọlọdẹ adugbo jọ, ni wọn ba jọ wọnu igbo Fidiwọ Alapako lọ, wọn n wa awọn afurasi ajinigbe naa.
Bi wọn ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn bẹrẹ si i sa lọ ninu igbo naa, ṣugbọn ọwọ ba awọn mẹta yii.
Nigba ti wọn fọrọ wa wọn lẹnu wo, awọn mẹtẹẹta jẹwọ pe awọn ti wa ninu igbo naa lati ọjọ mẹwaa sẹyin, to jẹ awọn n wa ọna tawọn yoo fi bọ si titi lai si iṣoro rara.
Wọn ni ohun to jẹ ko pẹ to bẹẹ kawọn too bọ sita lati ṣiṣẹ ibi ni pe awọn ọlọpaa maa n wa loju ọna yii pupọ. Wọn fi kun un pe mẹfa lawọn, wọn ni awọn mẹta to sa lọ yẹn ni oogun tawọn fi n ṣiṣẹ ijinigbe wa lọwọ wọn.
Iwadii awọn ọlọpaa ṣaaju fidi ẹ mulẹ pe awọn eeyan yii ni wọn wa nidii ijinigbe ẹnu ọjọ mẹta yii loju ọna ọhun. Ada loriṣiiriṣii lawọn ọlọpaa sọ pe awọn ri gba lọwọ awọn mẹta yii, wọn ni awọn ajinigbe naa sọ pe ọwọ awọn agbẹ tawọn ri ninu oko wọn lawọn ti gba a.
Wọn ti taari wọn sẹka itọpinpin to lagbara labala to n ri si ijinigbe nipinlẹ Ogun, gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe sọ.