Ajinigbe tun ji alufaa ijọ Katọliiki ati dẹrẹba rẹ gbe lọ

Adewale Adeoye

Titi di akoko ta a n koroyin yii jọ lọwọ, awọn ajinigbe kan ti wọn ji alufaa ijo Katọliiki ‘St Michaels Catholic’, Ẹni-Ọwọ Kingsley Ichie, to wa niluu Umuekebi, nijọba ibilẹ Isiala, nipinlẹ Imo, gbe ko ti sọ idi ti wọn ṣe ji alufaa ijọ ọhun lọ ati nnkan ti wọn fẹẹ gba lọwọ awọn ọmọ ijọ Ọlọrun naa pẹlu ẹbi rẹ ko too di pe wọn maa ju u silẹ pe ko maa lọ layọ ati alaafia.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aṣaalẹ ọjọ Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, lawọn ajinigbe ọhun lọọ dena de alufaa ijọ ọhun lagbegbe Orie-Ama, ti wọn si ji i gbe sa lọ pẹlu dẹrẹba rẹ ti wọn jọ wa ninu mọto naa.

Ọkan lara awọn ọmọ ijọ ṣọọṣi ọhun sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe awọn ajinigbe ọhun ko ti i sọ ohun ti wọn fẹẹ gba lọwọ ijọ bayii.

‘‘Adura la n gba lati ọjọ ta a ti gbọ pe awọn ajinigbe ọhun ti ji alufaa ijọ wa gbe, Ẹni-Ọwọ Kingsley ati dẹrẹba rẹ, Ọgbẹni Newman Uchenna,  ni wọn jọ wa ninu ọkọ lọjọ naa. Bi wọn ṣe duro lagbegbe Orie-Ama, ti wọn fẹẹ ra nnkan lawọn ajinigbe ọhun yọ si wọn, afi bii ẹni pe wọn n duro de wọn tẹlẹ ni, loju-ẹsẹ naa ni wọn ti ji wọn gbe sa lọ patapata,. Latigba naa la ko ti gburoo pe ki wọn pe wa lati sọ ohun ti wọn n fẹ lọwọ ijọ. Oju Ọlọrun la n wo bayii, adura wa si ni pe ki alufaa wa pẹlu dẹrẹba rẹ pada wa sile layọ ati alaafia ni’’.

Leave a Reply