Ajọ eleto idibo orileede Benin ṣabẹwo silẹ wa, eyi lohun to gbe wọn wa

Adewale adeoye

Awọn aṣoju ajọ eleto idibo orileede Benin Commission Electoral Nationale Autonomie’ (CENA) ti de sorileede Naijiria lati waa kọ ẹkọ lọwọ ajọ eleto idibo ilẹ wa, Mationla Electoral Commission (INEC), lori bi wọn yoo ṣe ṣeto idibo orileede wọn to n bọ lọna laipẹ yii.

Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun yii, ni awọn aṣoju ajọ eleto idibo orileede Benin ọhun de siluu Abuja, ti i ṣe olu ilẹ wa.

Alaga ajọ eleto idibo INEC lorileede wa, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, lo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin niluu Abuja, lasiko to n gba ikọ ẹlẹni mejila ọhun lati orileede Benin lalejo l’Abuja.

Oriṣii idibo mẹta ọtọọtọ lo maa waye lorileede naa lọdun 2026. Sugbọn ki wọn le loye kikun nipa bawọn naa ṣe maa ṣeto idibo wọn lọna igbalode to maa fi jẹ itẹwọgba lọdọ awọn araalu lawọn aṣoju ajọ CENA ọhun ṣe tete wa sọdọ awọn INEC bayii lati waa kẹkọọ lọdọ wọn.

Inu oṣu Kin-in-ni, ọdun 2026, ni ibo akọkọ sipo ileegbimọ aṣofin agba lorileede naa ati ti ijọba ibilẹ maa waye. Nigba to ba di oṣu Kẹrin ọdun naa, nibo sipo aarẹ orileede naa maa waye.

Lara awọn ẹkọ ti INEC maa kọ awọn ojugba wọn lati orileede Benin ni bi wọn yoo ṣe ṣohun gbogbo ni ilana ofin, tawọn ondije dupo ko fi ni i ri aleebu wọn di mu. Bi wọn yoo ṣe tẹ awọn ohun eelo ti wọn maa lo fun eto idibo ọhun, bi wọn aa ṣe gba awọn oṣiṣẹ sẹnu iṣẹ, ti wọn aa si kọ wọn lẹkọọ bi wọn aa ṣe ṣohun gbogbo ni ibamu pẹlu ẹkọ ti wọn ti kọ. Bakan naa ni eto iṣuna owo fun ajọ naa ati bi wọn aa ṣe sanwo fawọn araalu atawọn agbofinro ti wọn ba gbeṣẹ fun lasiko ibo, lilo imọ ẹrọ igbalode ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni ajọ INEC ṣetan lati ṣeranlọwọ gidi fawọn aṣoju ajọ CENA ọhun, ki wọn baa le ṣe aṣeyọri lẹnu iṣẹ ilu tijọba orileede wọn gbe le wọn lọwọ.

 

Leave a Reply