Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ẹka ajọ iṣọkan agbaye to n ri si iṣẹ akanṣe (UNOPS) ti bẹrẹ eto lati kọ ẹgbẹrun lọna aadọta ile olowo pọọku to jẹ ti igbalode sipinlẹ Ekiti.
Iṣẹ akanṣe naa, eyi ti Gomina Kayọde Fayẹmi ti fọwọ si, ni yoo waye fun bii ọdun mẹwaa, ẹka UNOPS ni yoo si pese owo ati irinṣẹ.
Ninu atẹjade ti igbakeji adari ẹka naa, Ọgbẹni Vitaly Vanshelboim, fi sita l’Ọjọbọ, Wẹsidee to kọja, eto naa yoo bẹrẹ lati fopin si wahala ile kikọ tawọn eeyan ni kaakiri ipinlẹ naa nitori ipenija owo.
Vanshelboim ni inu ẹka naa dun lati ṣe iru eto yii fun idagbasoke eto ilegbee nipinlẹ Ekiti ati Naijiria lapapọ, awọn ile tuntun wọnyi yoo si jẹ ile igbalode ti wọn fi ara ọtọ kọ.
O ni iṣẹ UNOPS ni lati ṣe akojọpọ owo lọdọ ileeṣẹ ati aladaani kaakiri, eyi to le to biliọnu meji dọla lapapọ, Ekiti yoo si darapọ mọ awọn ilu ti iru ile bẹẹ ti pọ ju lagbaaye.
O waa ni ijọba Ekiti ni yoo pese awọn ilẹ tawọn ile naa yoo duro le lori, bẹẹ ni wọn yoo pese ayika to daa fun awọn ti yoo lọwọ si eto idagbasoke ọhun.
Nigba to n fi idunnu rẹ han si iṣẹ akanṣẹ naa, Fayẹmi ni lara awọn ileri tijọba ṣe fun awọn eeyan Ekiti lo ti n wa si imuṣẹ yii, eyi to ni i ṣe pẹlu igbaye-gbadun.
O ni awọn ile olowo pọọku wọnyi yoo ni awọn eroja ti yoo maa pese ina nipasẹ oorun, eroja to n dena ẹ̀fọn ati bẹẹ bẹẹ lọ, ati pe eto naa yoo pese iṣẹ fawọn eeyan lọpọ yanturu.