Akapo ṣọọṣi Winners kowo jẹ, ladajọ ba sọ ọ sẹwọn ọdun mẹta

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn lọọ sọ Pasitọ Afọlabi Samuel, ti ijọ Winners Chapel, sẹwọn ọdun mẹta lori pe o ko owo ṣọọṣi jẹ.

Adajọ Mojisọla Dada lo paṣẹ yii lori ẹsun onikoko meji ti wọn fi kan ọkunrin naa pe o ji ẹgbẹrun lọna aadọrun-un owo dọla ati miliọnu mẹrin aabọ naira ko nileejọsin ọhun.

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC, ni wọn lo wọ pasitọ yii lọ sile-ẹjọ. Ninu ẹsun ọhun ni wọn ti sọ pe, “Samuel, ẹni ti i ṣe akapo ṣọọṣi ati Blessing Kọlawọle, ọkan lara awọn oṣiṣẹ Covenant University, to ti sa lọ bayii, lo ipo wọn lati fi ji owo ileejọsin ko sapo ara wọn.

Ninu idajọ ti Arabinrin Mojisọla Dada gbe kalẹ lo ti sọ pe Samuel jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an. Bẹẹ ni Ọgbẹni Rotimi Ogunwuyi, ẹni to duro gẹgẹ bii agbẹjọro fun un bẹ Adajọ ki wọn din ọdun ti yoo lo lẹwọn ku nipa ṣiṣi oju aanu wo o.
Ninu ẹbẹ ẹ naa lo ti sọ pe onibaara oun ti kabaamọ aṣiṣe rẹ, eyi naa lo si mu un sọ pe oun gba pe oun jẹbi dipo bo ti kọkọ sọ pe oun ko jẹbi tẹlẹ.

Pẹlu ẹbẹ naa ni Amofin Rotimi fi sọ pe ọkunrin ti oun n ṣoju fun yii naa lo maa n sanwo ileewe awọn ọmọ ẹ, oun naa si lo n tọju awọn obi ẹ ti wọn ti darugbo.

Ẹbẹ yii lo mu adajọ paṣẹ ko sanwo itanran miliọnu kan naira, ko si da awọn owo to ji ko pada, iyẹn ẹgbẹrun lọna aadọrun-un dọla ($90,000) ati owo to fẹẹ to miliọnu meji abọ naira (N2,358,000) to jẹ owo ṣọọṣi ọhun.

 

Leave a Reply