Akeem atọrẹ ẹ fo mọ ọkọ akẹru lori ere, wọn ba fibọn ja a gba

Faith Adebọla

Yoruba bọ, wọn lohun a ba mọ ọn iṣe, bii idan ni i ri, bii majiiki ni iṣẹ adigunjale jẹ fun awọn afurasi ọdaran kan tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ tẹ yii, Akeem Adeleke, ati ọrẹ ẹ ti wọn loun ti ṣeku pa ara ẹ. Ọna ara-ọtọ lawọn gbe iṣẹẹbi wọn gba, awọn ki i jale ọkada tabi ọkọ ayọkẹlẹ rara, niṣe ni wọn maa n fo mọ awọn ọkọ akẹru nibi ti ọna ko ba ti daa, tawọn ọkọ naa ba ti n fẹsọ rin, wọn yoo si yọbọn si awakọ, wọn aa le e bọ silẹ, n ni wọn yoo ba wa ọkọ atẹru lọ ni tiwọn, amọ ọwọ palaba wọn ti segi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fiṣẹlẹ ọhun to Alaroye leti ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sọ pe ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ta a wa yii, ni dẹrẹba ọkọ akẹru kan sare jannajanna lọọ ba awọn ọlọpaa ti wọn n patiroolu ọna marosẹ Eko s’Ibadan, bo ṣe n rojọ lo kawọ mọri, o ni ṣadeede lawọn gende meji adigunjale kan fo mọ ọkọ akẹru toun n wa lasiko toun tẹ siloo fun koto kan lati wọ Ibadan, n ni wọn ba ṣilẹkun ọkọ mọ oun lẹgbẹẹ, wọn yọ ibọn soun, wọn si fipa gba ọkọ naa lọwọ oun lẹyin ti wọn ti ti oun bọọlẹ. O ni niṣeju oun ni wọn fi lọri ọkọ naa pada, ti wọn mori le ọna Eko, bẹẹ awọn ẹru ileeṣẹ kan toun ko lo wa ninu ọkọ akẹru ọhun.

Lọgan lawọn ọlọpaa naa ṣina ọkọ wọn, wọn ni ki dẹrẹba to kegbajare wa naa tẹle awọn, n ni wọn ba ṣina bolẹ, wọn bẹrẹ si i tọpasẹ awọn adigunjale naa lọ. Nigba to ku diẹ ki wọn de Eko, wọn ri ọkọ akẹru ọhun lọọọkan, lẹgbẹẹ titi, wọn ni bawọn adigunjale meji yii ṣe ri i pe ọkọ ọlọpaa n bọ lẹyin wọn, ara fu wọn pe afaimọ ni ki i ṣe awọn ni wọn n le bọ, eyi lo mu ki wọn sare paaki ọkọ naa sẹgbẹẹ titi. Afurasi adigunjale to wa ọkọ naa ko ṣe meni ṣe meji, niṣe lo bẹ bọọlẹ lori ere lati sa lọ, amọ ko ri kinni ọhun ṣe, wọn ni niṣe lo fori sọlẹ nigba to bẹ bọọlẹ, oju-ẹsẹ lo ja pitipiti latari bo ṣe ṣera ẹ leṣe, nigba tawọn ọlọpaa yoo si fi debẹ, o ti ku fin-in fin-in.

Akeem ko ribi bẹ ni tiẹ, inu ọkọ naa ni wọn ka a mọ, ti wọn si fi pampẹ ọba mu un, n ni wọn ba lọọ ti i mọ ahamọ lẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ewu-Oliwo.

Nigba ti DPO teṣan Ewu-Oliwo, CSP Toyọsi Bello, gbọ sọrọ yii, oun atawọn ẹmẹwa ẹ tẹkọ leti de ibi iṣẹlẹ naa, wọn ba oku adigunjale to bẹ lori ere naa nibi to na gbalaja si, n ni wọn ba palẹ ẹ mọ lọ sile igbokuu-si ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun Fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, to wa l’Ago-Iwoye.

Lara awọn irinṣẹ tawọn afurasi naa n lo ti wọn ri gba lọwọ wọn ni ibọn agbelẹrọ pompo kan, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹta, foonu itel meji, ati ọpọ oogun abẹnugọngọ ti wọn so mọra.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Frank Mba, ti paṣẹ pe ki wọn taari Akeem si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to rinlẹ lori ọrọ yii. Bẹẹ lo ṣekilọ pe kawọn ọdaran tete wabi gba kuro nipinlẹ Ogun.

Leave a Reply