Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn alaṣẹ Fasiti Ifẹ ti fidi rẹ mulẹ pe ọkan lara awọn akẹkọọ wọn, Adedeji Emmanuel, ti jade laye latari majele (Snipper) to gbe jẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Alukoro ileewe naa, Abiọdun Ọlarewaju, ṣalaye pe ipele keji ni ẹka Iṣakoso ati Iṣiro owo (Management and Accounting Department) ni Emmanuel wa, ko si si ẹni to le sọ ni pato idi to fi gbe igbesẹ to gbe naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn alaṣẹ ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣewadii ohun to ṣẹlẹ si Emmanuel gan-an to fi gbe oogun jẹ.
Ọlarewaju waa ke si awọn akẹkọọ ti wọn ba n la ohun kan kọja tabi ti wọn ni iporuuru ọkan lati tete maa lọ si ẹka igbaniniyanju nileewe naa dipo ki wọn maa gbẹmi ara wọn.
Iwadii Alaroye fihan pe lagbegbe Conference Center, ni Emmanuel ati ọrẹ rẹ kan ti gbe oogun naa jẹ, ṣugbọn o tete ṣiṣẹ lara Emmanuel, o si ti ku ki wọn too gbe e deleewosan.
A gbọ pe ẹni keji rẹ n gbatọju lọwọ nileewosan, ti oju rẹ si ti n walẹ diẹdiẹ.