Stephen Ajagbe, Ilorin
Iwe ti EFCC fi wọ ọ lọ sile-ẹjọ ṣalaye pe ninu oṣu kọkanla, ọdun 2019, ni ọdaran naa fọgbọn gba ẹgbẹrun marundinlaaadọta lọwọ Anjọrin Oluwabukọlami Eniọla, lati ba a wa ile, ṣugbọn ti ko mu adehun ṣẹ.
Akanti banki GTb kan, 0452652140, to jẹ ti Hassan Adefẹmi Daniel lo ni ko san owo naa si. Wọn ni bo ṣe maa n gba owo lọwọ awọn akẹkọọ yooku niyẹn lai ba wọn wa ile.
Nigba tile-ẹjọ ka ẹsun rẹ si i leti, ọdaran naa loun jẹbi. Agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni J.A. Ayinde, rọ ilẹ-ẹjọ lati foju aanu wo o, ki wọn si din ijiya rẹ ku.
Ṣugbọn Agbẹjọro EFCC, Andrew Akoja, ni oun yọnda idajọ le ilẹ-ẹjọ lọwọ lati paṣẹ to ba yẹ lori ẹjọ naa.
Adajọ Oyinloye kọ lati gba ẹbẹ rẹ. O ni yatọ si ẹwọn oṣu mẹsan-an ti ọdaran naa maa lọ, o tun gbọdọ san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ati marun-un Naira, N105,000, gẹgẹ bii owo itanran. Eyi to ni yoo jẹ arikọgbọn fawọn to ba n hu iru iwa bẹẹ tabi ti wọn ni i lọkan lati ṣe nnkan bẹẹ.