Stephen Ajagbe, Ilorin
Adajọ Sikiru Oyinloye tile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, ti ju akẹkọọ-jade ileewe Fasiti KWASU, Ahmed Bọlaji, sẹwọn oṣu mẹfa gbako fun ṣiṣe jibiti ori ẹrọ ayelujara.
Ọmọ ọdun mọkanlelogun naa lajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu baṣbaṣu, EFCC, wọ lọ sile-ẹjọ fẹsun pe o tan oyinbo alawọ funfun kan lati le gba owo lọwọ ẹ.
Bọlaji to n pe ara rẹ ni Rosemary, to si n lo foto obinrin lori ẹrọ ayelujara lati maa fi lu awọn ọkunrin ni jibiti lọwọ tẹ loṣu kin-in-ni, ọdun 2021.
Nigba ti wọn ka ẹsun yii si i leti, akẹkọọ-jade nipa imọ ibaraalu sọrọ ati igbohun-safẹfẹ (Mass Communication) naa ni loootọ loun jẹbi.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ EFCC to mu ọdaran naa, Loveday Godwin, ṣalaye pe ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 lọwọ tẹ Bọlaji lẹyin tawọn kan ta ileeṣẹ awọn lolobo.
Onitọhun tẹsiwaju pe ọdaran naa gbiyanju lati lu ọkunrin oyinbo kan, Shawn Smith, ni jibiti owo ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.
Agbẹjọro EFCC, Ọgbẹni Sẹsan Ọla, ko foonu meji ti Bọlaji fi n ṣe jibiti atawọn ẹri mi-in to fi han pe o hu iwa naa siwaju ile-ẹjọ, adajọ si tẹwọ gba a gẹgẹ bii ẹri.
Ọgbẹni Ọla ni niwọn igba ti Bọlaji ti jẹwọ pe loootọ loun jẹbi, ki ile-ẹjọ dajọ rẹ kiakia.
Adajọ Oyinloye ni niwọn igba ti agbefọba ti fidii ẹjọ naa mulẹ, ko si ariyanjiyan rara pe ọdaran naa gbọdọ jiya ẹṣẹ rẹ.
O ni ki ọdaran naa san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira owo itanran, tabi ko lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa.