Monisọla Saka
Akẹkọọbinrin ile iwe giga Poli Yaba College of Technology (Yabatech), to wa lagbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, ti wa leti bebe ọrun bayii pẹlu bo ṣe gbe oogun oloro kan ti wọn fi n pa ẹfọn ati kokoro, Sniper mu, nitori pe ọrẹkunrin ẹ ja a si ọlọpọn, tiyẹn loun ko fẹ ẹ mọ.
Ẹka ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa itaja, Marketing, ni ọdọmọdebinrin ọhun wa nileewe naa. Ọkan ninu awọn ti wọn jọ n gbe ninu yara kan naa ninu ọgba ileewe wọn lo pariwo sita fawọn ẹgbẹ wọn pe Deborah n ku lọ o!.
Alabaagbe Deborah yii ṣalaye pe o ti kọkọ ka fidio ara ẹ nibi to ti n mu Sniper sinu fidio silẹ, o si fi ṣọwọ si afẹsọna rẹ ọhun ki oro majele naa too mu un.
Ninu fọnran ti ọkan ninu awọn akẹkọọ ileewe yii gbe sori ayelujara l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun yii, lawọn akẹkọọ naa ti kora wọn jọ si ẹnu ọna yara ti Deborah wa, ti ọkan ninu wọn si n pariwo pe Deborah fẹẹ da awọn obi ẹ loju nitori ọkunrin lasan.
Oriṣiiriṣii ọrọ ni wọn n sọ labẹlẹ ninu fidio ọhun, ọmọbinrin to wa nipele ẹkọ kin-in-ni yii, Deborah, ni wọn si n da lẹbi. Ẹni kan ni, “Bawo lo ṣe maa mu Sniper nitori Adam? Iwọ lọ n gbe majele jẹ nitori Adam lasanlasan?
Ẹni kan to kọ ọrọ si abẹ fidio ọhun lori ẹrọ Instagram pe, “Agba ko kan ọgbọn o, a nilo imulọkanle gidi gan-an lorilẹ-ede yii, nitori nnkan o rọgbọ, ita le”.
Ẹni kan to n jẹ Mr. mor naa kọ ọ pe, “Ara awọn idi temi ko ṣe fara mọ kawọn ọmọ keekeeke yii maa ni afẹsọna niyi o, nitori pẹlu ayọ ati idunnu lo fi maa n bẹrẹ, ṣugbọn to maa n pari pẹlu ẹdun ọkan ati ibanujẹ”.
Israel Innocent ni, “Gbogbo ohun yoowu ko jẹ, mi o lero pe oju lasan leleyii o, tori bawo lọmọ to wa nipele ẹkọ kin-in-ni, ṣe maa tori ifẹ para ẹ, o ma ṣe o! Nigba teeyan ko ba si ti mọ ohun to waye waa ṣe, bi wọn ṣe maa n fi ẹmi ara wọn ṣofo niyẹn” .
Bo tilẹ jẹ pe wọn sare gbe e digbadigba lọ silewosan ileewe wọn, loju-ẹsẹ lawọn yẹn ti kọwe pe ki wọn gbe e lọ si ọsibitu ileewe awọn ologun, Millitary Hospital Yaba, fun itọju to peye. Ko sẹni to le sọ iru ipo tọmọ naa wa lasiko ta a n kọ iroyin yii.