Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Lowurọ kutu, ọjọ Aje, Mande, ọsẹ yii, ni ọlọkada meji kọ lu ara wọn l’Opopona Ojuku, niluu Ọffa, ọdọbinrin to jẹ ọmọ ileewe Poli ijọba apapọ tilu Ọffa (Federal polytechnic Ọffa), kan ati ọlọkada meji si da lẹsẹ.
ALAROYE gbọ pe awọn ọlọkada mejeeji ọhun ni wọn gbe ero sẹyin, ti wọn si n sare asapajude, eyi to mu ki ijamba naa waye, wọn gba ara wọn, awọn mẹrẹẹrin to wa lori ọkada ṣubu, ọmọ ileewe kan ati ọlọkada mejeeji si da lẹsẹ.
Wọn ti ko awọn mẹrẹẹrin lọ sileewosan jẹnẹra to wa niluu Ọffa, fun itọju to peye, awọn ọlọpaa si ti gbe awọn ọkada wọn lọ si teṣan wọn.