Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Akẹkọọ-jade ileewe gbogboniṣe ilu Iree, nipinlẹ Ọṣun, Samson Ajao, ti fi itan tuntun balẹ lagbaaye bayii pẹlu bo ṣe fi odidi wakati okoolelugba o din marun-un ti aropọ rẹ ku si ọjọ mẹwaa, kawe lojuu gbogbo aye.
Igbesẹ naa ni Samson, ẹni ti awọn ẹgbẹ rẹ n pe ni Impeccable, bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun yii, ninuu gbọngan nla kan lagbegbe Ogo-Oluwa, niluu Oṣogbo.
Oniruuru awọn eeyan nla nla nipinlẹ Ọṣun ni wọn ṣabẹwo si Samson lati fun un ni iwuri laarin ọjọ mẹwaa to fi kawe naa. Lara wọn ni ọkan lara awọn iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun, Erelu Ngozi Adeleke, Olori ileegbimọ aṣofin, Ọnarebu Adewale Ẹgbẹdun, Ọnarebu Bamidele Salam, Kọmiṣanna fun eto ẹkọ, Ọjọgbọn Dipọ Eluwọle, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bo tilẹ jẹ pe igba ati mẹrinla wakati (214 hours) ni Samson kede nibẹrẹ pe oun yoo fi kawe naa, sibẹ, o sun un siwaju, ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, si ni wakati okoolelugba o din marun-un (215 hours) pe, to si fopin si i.
Pẹlu ariwo ayọ lawọn ololufẹ ọmọkunrin naa ti wọn wa ninu gbọngan nla ọhun fi ki i ku iṣẹ, koda, ṣe ni wọn gbe mọto jade, ti wọn si to lọwọọwọ kaakiri ojuupopo niluu Oṣogbo, lati fi bu ọla fun un.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ to gbe yii, Samson sọ pe inu oun dun pe oun ṣe aṣeyọri ifẹ ọkan oun, nitori ohun to wu oun ni ki aṣa iwe kika pada si ọkan awọn ọdọ lorileede yii.
O ni o wu oun ki awọn ọdọ maa ṣamulo awọn ibudo ile iṣewelọjọ si (Library), lati maa kawe loorekoore, ki wọn le ni oye kikun nipa ayika wọn, dipo ki wọn maa lo asiko wọn fun awọn nnkan ti ko nitumọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọkunrin kan, Rysbai Isakov, lo wa ninu akọsilẹ Guiness World Records, pe o kawe fun wakati to pọ ju tẹlẹ.
Ni Bursa, ni orileede Turkey, ni Isakov ti fitan balẹ lọdun 2022, nigba to kawe fun wakati ọgọfa o le mẹrin (124 hours).
Ni bayii ti Samson ti fi wakati okoolelugba o din marun-un ka tiẹ, o ni oun ti fi akọsilẹ eto naa ranṣẹ si awọn alakoso Guinness World Records fun ayẹwo.