Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn alaṣẹ ileewe Fasiti tipinlẹ Kwara (Kwara State University), to wa niluu Malete, nijọba ibilẹ Móòrò, ti ni gende-kunrin kan, Aiyeyẹmi Sulaiman Ọlayinka, tawọn ọlọpaa kan lu pa lagbegbe biriiji Tankẹ, niluu Ilọrin, ki i ṣe akẹkọọ awọn.
Ninu atẹjade kan ti Adele adari ẹka to n gbe iroyin jade nileewe ọhun, Ọmọwe Saeedat Aliyu, fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti fidi ẹ mulẹ pe oloogbe naa ki i ṣe akẹkọọ awọn.
O ni lati ọdun 2018/2019, lasiko ti oloogbe Ọlayinka, wa ni ipele ọlọdun keji (200 level), lo ti fi ileewe awọn silẹ.
Fun idi eyi, ko si ootọ kankan ninu iroyin tawọn eniyan n gbe kiri pe akẹkọọ KWASU ni, bo tilẹ jẹ pe loootọ lo ti figba kan jẹ akẹkọọ awọn lẹka Statistics, ṣugbọn ninu akọsilẹ ileewe, o ti kuro lọgba.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu yii, ni wọn ni awọn agbofinro mẹta kan lu oloogbe Ọlayinka pa, tileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa si ti fi iroyin lede pe ọwọ ti tẹ awọn eeyan wọn to huwa buruku ọhun, tawọn si ti fi wọn ṣahaamọ, bo tilẹ jẹ pe wọn o fi orukọ awọn ọlọpaa ọhun lede.
Awọn alaṣẹ KWASU, ti waa ni awọn kẹdun pẹlu mọlẹbi oloogbe, ti wọn si gbadura pe ki Ọlọrun Adẹdaa rọ awọn obi rẹ loju, ki wọn le fara da adanu naa.