Ọlawale Ajao, Ibadan
Musiliu Haruna Iṣọla lo kọrin pe “iṣẹ Oluwa ko sẹni to ye, iṣẹ Oluwa ju taafa lọ”. Bo ṣe ri gan-an ree nigba ti akẹkọọ kan to ni ipenija eti, Omidan Aanuoluwapọ Ọmọlẹyẹ Busade, ṣe aṣeyọri ti ẹgbaagbeje akẹkọọ to jẹ abarapaa ko le ṣe pẹlu bo ṣe gba igbelewọn maaki to ga ju lọ tawọn Oloyinbo n pe ni First Class Honour ni Unifasiti Ibadan (UI).
Ọmọbinrin to kẹkọọ jade lẹka to n ri si eto ẹkọ ati eto itunniṣe fawọn akanda eeyan lẹka imọ ijinlẹ sayẹnsi ( Department of Special Education & Rehabilitation on Science) ni Fasiti ibadan, lo wa lara awọn ọmọwe akẹkọọ ti awọn alakooso fasiti naa bọ lọwọ fun imọriri ọpọlọ pipe wọn ninu ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye to waye ninu ọgba fasiti naa lọsẹ to kọja.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Aanuoluwapọ nikan ṣoṣo lo jẹ akanda ninu gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn jọ n ṣe kọọsi kan naa titi dori awọn ọgọọrọ eeyan to n ṣe kọọsi mi-in lẹka eto ẹkọ to wa.
Ṣugbọn si iyalẹnu awọn eeyan, aigbọrọ ọmọbinrin yii jẹ ko dènà aṣeyọri ẹ, kaka bẹẹ, oun lo fakọyọ ju lọ laarin awọn ẹgbẹ ẹ.
Lara awọn ami-ẹyẹ to tun gba ni akẹkọọ to ṣe daadaa ju lọ ninu imọ ẹkọnọmiiki, akẹkọọ to tayọ ju lọ lẹka eto ẹkọ ẹ ati ẹni to ṣe daadaa ju lọ laarin awọn akẹkọọ fasiti naa ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan.
Yatọ si pe Aanuoluwapọ mọwe, gbogbo awọn ẹgbẹ ẹ ni wọn royin rẹ pe ki i ṣẹbun iwe nikan lo ni, wọn lọmọbinrin ọlọpọlọ pipe naa tun maa n tayọ ọpọlọpọ ẹgbẹ ẹ ninu ere idaraya atawọn nnkan mi-in to yatọ si iwe.