Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ni ibamu pẹlu ileri to ṣe lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ APC to waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Gomina Rotimi Akeredolu ti bẹrẹ igbesẹ ilaja pẹlu awọn to fidi-rẹmi ninu eto ibo naa.
Lara awọn to ṣabẹwo pajawiri si lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, oni ni: Oloye Oluṣọla Oke, Isaac Kekemeke ati Ambasadọ Oluṣọla Iji.
Akeredolu rọ gbogbo awọn tinu n bi ọhun lati fọwọ wọnu, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu rẹ̣, ko le rọrun fun ẹgbẹ APC lati jawe olubori ninu eto ibo gomina to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun yii.
O ni ọrẹ ni gbogbo awọn lati ọjọ pipẹ, bẹẹ ni ko si yẹ ki wọn gba ọrọ oṣelu laaye lati tu wọn ka.
Ni kete ti wọn pari eto idibo yii ni Kekemeke ti fi atẹjade kan sita, ninu eyi to ti fi aidunnu rẹ han si ọna ti wọn gba ṣeto naa.
Akọwe ijọba ipinlẹ Ondo tẹlẹ ri ọhun ni ọna ti wọn fi ṣeto idibo naa fihan pe, awọn asaaju ẹgbẹ APC lorilẹ-ede yii ti pinnu ati fun Akeredolu ni tikẹẹti idije lẹẹkeji lai fi ti awọn yooku ṣe.
O ni bo tilẹ jẹ pe inu oun ko dun si abajade eto idibo naa, sibẹ, oun ko ṣetan ati kuro ninu ẹgbẹ APC tabi ki oun pe ẹnikeni lẹjọ.