Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ṣe ni papa iṣere Gani Fawẹhinmi to wa l’Alagbaka, niluu Akurẹ, kun fọfọ fawọn eeyan lasiko ti Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ṣe ifilọlẹ ẹsọ alaabo Amọtẹkun ẹka tipinlẹ Ondo l’ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.
Inu oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni Alakooso ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, kede pe aaye ti wa fawọn eeyan lati waa forukọ silẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ Amọtẹkun.
Osu diẹ sẹyin ni wọn bẹrẹ idanilẹkọọ fun gbogbo awọn to fẹẹ kopa, oni ọjọ Isẹgun, Tusidee, ni wọn si feto si lati ṣayẹyẹ ikẹkọọ-jade fawọn to yege ninu idanilẹkọọ naa.
Akeredolu lo asiko ifilọlẹ naa lati fawọn araalu lọkan balẹ lori awọn ipenija eto aabo to n sẹlẹ lọwọ.
O ni ọrọ eto aabo nipinlẹ Ondo ko ni i ri bii ti tẹlẹ mọ nitori pe ko sibi tawọn oniṣẹẹbi wọnyi fẹẹ sapamọ si tọwọ ko ni i tẹ wọn.
Ọkunrin yii ni ero awọn eeyan kan nigba toun kọkọ dabaa ṣiṣe agbekalẹ ẹgbẹ Amọtẹkun niluu Ibadan ni ibẹrẹ ọdun ta a wa yii ni pe ṣe loun fẹẹ lo wọn ki wọn le ṣiṣẹ fun saa keji oun lasiko idibo. O ni oun fi n da awọn eeyan loju pe ikọ Amọtẹkun ko ni i woju ẹnikẹni to ba fẹẹ huwa jagidijgan ninu eto idibo to n bọ lọna.
Ninu ọrọ tirẹ, aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, Ọnarebu Success Taiwo Torhukerhijo, bẹ ijọba Akeredolu lati ranti awọn eeyan ori omi ninu eto Amọtẹkun naa.