Monisọla Saka
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, to ti wa lori aisan lati bii oṣu meloo kan bayii, ti wọn si ti gbe e lọ si oke okun fun itọju to peye, ti kọ lẹta ranṣẹ sile l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun yii.
Ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, lo ti fẹmi imoore rẹ han si Aarẹ Bọla Tinubu, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, (APC), atawọn eeyan ipinlẹ Ondo, fun atilẹyin lọlọkan-o-jọkan ti wọn fun un latigba to ti dero ileewosan.
Bakan naa lo sọ bi ọkan rẹ ṣe ti n fa ile si. O fẹdun ọkan rẹ han sawọn eeyan ipinlẹ Ondo, pe o ti da bii koun ti waa ba wọn, amọ ni kete tawọn dokita ba ti fidi ẹ mulẹ pe oun le maa lọọle, ti wọn si tu oun silẹ, loun yoo dari pada sorilẹ-ede yii.
Apa kan atẹjade rẹ, ti Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Bamidele Ademọla Ọlatẹju, fi sita sọ pe, “Pẹlu ọkan to kun fun ọpẹ ati ẹmi imoore ni mo fi kọ lẹta mi yii lati dupẹ lori aduroti, adura ati ọrọ iyanju yin lasiko ti ara mi ko ya yii. Mo dupẹ pupọ lọwọ yin, paapaa ju lọ awọn eeyan daadaa ipinlẹ Ondo.
” Mo tun dupẹ pataki lọwọ Aarẹ wa, Aṣiwaju Bọla Tinubu, atawọn eeyan wọn, to fi mọ ẹgbẹ oṣelu wa, APC, awọn gomina yooku ti wọn jẹ ẹlẹgbẹ mi, awọn igbimọ alaṣẹ ipinlẹ atawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin fun atilẹyin wọn.
Gẹgẹ bi ara mi ṣe ti n pada bọ sipo, inu mi n dun pe ma a tun darapọ mọ yin, bẹẹ lemi naa yoo duro laarin yin laipẹ yii. Ma a de pada si aarin yin ni kete ti wọn ba ti ni ara mi ti le daadaa”.
Akeredolu tun fi awọn eeyan ipinlẹ Ondo lọkan balẹ, pe oun ṣi duro ileri oun lati sin wọn, ati lati ṣiṣẹ fun ayipada ipinlẹ naa, toun ba ti pada sile.
Tẹ o ba gbagbe, lati ibẹrẹ ọdun yii, ni aisan ti da gomina ọhun gunlẹ, debii pe ko lanfaani lati maa ṣe ojuṣe rẹ ninu ọọfiisi mọ, tawọn eeyan si n gbe ahesọ kiri pe ọkunrin naa ti ku.