Akeredolu ni kawọn akẹkọọ maa wọ aṣọ ilẹ wa lọ sileeewe l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti fontẹ lu aṣọ ilẹ wa ni wiwọ lọ sileewe fun gbogbo awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ ati girama nipinlẹ Ondo.

Igbesẹ tuntun ọhun ni wọn fọwọ si lasiko ti wọn n ṣepade igbimọ apaṣẹ ijọba ipinlẹ, eyi ti wọn ṣe lọfiisi gomina to wa ni Alagbaka, l’ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Ninu ipade ọhun ni wọn ti paṣẹ fun gbogbo akẹkọọ patapata lawọn ileewe alakọọbẹrẹ ati girama, yala ti ijọba tabi ti awọn aladaani lati maa wọ aṣọ ilẹ wa ni gbogbo ọjọ Ẹti, Furaidee.

Bakan naa ni wọn tun pọn ọn ni dandan fawọn oṣiṣẹ ni gbogbo ileeṣẹ to jẹ ti ijọba pe o ti deewọ fun eyikeyii ninu wọn lati maa wọ aṣọ miiran to yatọ si aṣọ ilẹ wa l’ọjọ Ẹti, Furaidee.

Ẹẹkan pere laarin ọdun kan lawọn akẹkọọ ọhun maa n wọ aṣọ ilẹ wa lasiko ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ ọjọ iranti aṣa, eyi ti wọn ti bẹrẹ lati bii ọdun marun-un sẹyin.

Leave a Reply