Faith Adebọla
Gẹgẹ bii orukọ ẹ, gbajugbaja onkọrin ẹmi nni, Adeyinka Alaṣeyọri, ti tun ṣe aṣeyọri mi-in, aṣeyọri nla si ni, obinrin naa ti bimọ obinrin lanti-lanti kan, o ti di iya ikoko bayii, orin ọpẹ lo si gba ẹnu ẹ kan s’Eledua!
Gẹrẹ ti obinrin to lohun dundun to maa n kọrin yii sọ ẹru ayọ naa kalẹ lo ṣe ikede ayọ abara-tintin naa lori opo instagiraamu rẹ, lafẹmọju ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa yii, lati fi idunnu rẹ han.
Ṣe inu ẹni ki i dun ka pa a mọra, ko digba ti wọn ba n sọ fẹnikan lati mọ bi inu olorin yii ṣe dun to, oriṣiiriṣii fọto igba to diwọ-disẹ sinu, fọtọ oun atọkọ ẹ pẹlu akọbi ẹ, ati ọrọ ṣoki to kọ sabẹ fidio naa ti fi ayọ ọkan rẹ han, o ni:
“Ọlọrun Ọba lo ni gbogbo ogo o. O ti ja sọpẹ nigbẹyin, ọmọbinrin ni o!”
Ohun to tubọ mu kinu obinrin yii dun dẹyin ni pe o ti bimọ ọkunrin kan tẹlẹ, o si ti waa bimọ obinrin bayii, ko kuku si ẹkẹta ọmọ.
Bi Alaṣeyọri ṣe ṣe ikede yii lawọn ololufẹ ẹ ti n ki i ni mẹsan-an mẹwaa, wọn n ba a yọ, wọn ki i ku ewu o, wọn ni Ọlọrun ẹ wa lẹyin ẹ gidi, tori alaṣeyọri ni loootọ.
Ọpọlọpọ awọn gbajumọ oṣere tiata bii Dayọ Amusa, Bimbọ Success, Aisha Lawal, Ṣeyi Ẹdun, Adediwura, Jide Awobọna, Kẹmi Korede, Wolii Arole, Jaye Kuti ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti ba Alaṣeyọri yayọ ọmọ tuntun.
Ọkan pataki ninu awọn to kọ ọrọ idupẹ tinu awọn eeyan dun si ju ni ilu-mọ-ọn-ka olorin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi. O ni: “Ọmọbinrin jojolo, kaabọ saye o, ẹ kuu oriire,” n lawọn ololufẹ wọn ba n ki Tọpẹ pe bo ṣe daa lo ṣe yẹn, gbogbo ẹni n fẹre ni i ba onire yọ.