Faith Adebọla
Pẹlu eto to waye nileegbimọ aṣofin agba lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa yii, Gomina ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ, Godswill Akpabio ti di olori awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba, iyẹn sẹneeti latari bawọn ẹlẹgbe rẹ ṣe yan an pe oun ni ko maa dari awọn.
Ọkunrin, to ti figba kan jẹ minisita fun ọrọ agbegbe Niger –Delta naa fi ẹyin oludije ẹgbẹ rẹ, toun jẹ gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹri, Abdulaziz Yari, janlẹ.
Nnkan bii aago mẹsan-an owurọ ni eto idibo lati yan awọn ti yoo maa dari ileegbimọ aṣofin agba ọhun bẹrẹ, bo tilẹ jẹ pe aago mẹwaa ni wọn kọ sori iwe ikesini ti wọn ti ha fawọn eeyan.
Ọgbẹni Sani Tambuwal, to jẹ akọwe fun ileegbimọ aṣofin agba naa lo ṣalaga eto iyansipo ọhun, oun lo si tukọ bo ṣe lọ si.
Nigba ti Tambuwal pe fun aba lati yan ẹni ti yoo jẹ olori wọn, Sẹnetọ Alli Ndume, lati ẹkun idibo Guusu Borno dabaa Akpabio fun ipo olori, oju-ẹsẹ si ni Sẹnetọ Elisha Abbo lati ẹkun idibo Ariwa Adamawa dabaa Yari pe ki wọn yan an sipo, eyi lo mu ki eto idiboyan bẹrẹ.
Lẹyin tawọn aṣofin naa ti to jade, lọkọọkan ejeeji, ni ilana ABD gẹgẹ bii lẹta akọkọ to ṣaaju orukọ koowa wọn, wọn yan awọn meji lati igun ọkọọkan awọn oludije naa, pe ki wọn le jọ ka awọn ibo naa, ki wọn si ṣe aropọ rẹ.
Lasiko yii lawọn aṣofin aṣẹṣẹdiboyan gbogbo ọhun lọ fun isinmi ra-n-pẹ, nigba ti wọn yoo wọle pada lati isinmi, wọn ti pari eto kika ati aropọ ibo, Tambuwal lo si kede esi ibo ọhun, o ni aropọ ibo mẹtalelọgọta (63) ni Akpabio ni, nigba ti Yari ni aropọ ibo mẹrindinlaaadọta (56), bẹẹ lo ṣe kede Sẹnetọ Godswill Akpabio bii ẹni to gbegba oroke.
Lọgan naa ni eto iburawọle ti tẹle e, ti wọn si ti mura ẹyẹ fun un gẹgẹ bii olori awọn aṣofin agba ati apapọ ileegbimọ aṣofin mejeeji nilẹ wa.
Ṣe o ti to ọjọ mẹta ti wọn ti wa lẹnu ipolongo ibo fun awọn aṣofin ẹgbẹ wọn lati dibo yan wọn gẹge bii ẹni ti yoo maa ṣe olori wọn. Ṣugbọn o jọ pe ọkunrin to ti ṣe minisita ri yii ni aayo Aarẹ Bọla Tinubu, oun naa lo si jawe olubori.
Bakan naa ni ọkan ninu awọn aṣofin ọhun, Alli Ndume, sọ fawọn oniroyin laipẹ yii pe ọkunrin naa loun n polongo ibo fun nitori oun ni Aarẹ awọn fẹ, oun paapaa lo si ran oun niṣẹ lati ri i pe ọkunrin yii jawe olubori gẹgẹ bii olori wọn tuntun.