Faith Adebọla, Eko
Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nigba kan, Oloye Bọde George, ti sọrọ nipa erongba Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati dije fun ipo aarẹ orileede wa lasiko eto idibo to n bọ lọdun 2023, o ni ala irọ ni Tinubu n la, ohun ti ko le ṣẹlẹ ni.
Ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, ni Tinubu bawọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade pataki kan toun ati Aarẹ Muhammadu Buhari tilẹkun mọri ṣe l’Abuja, pe oun ti sọ erongba oun lati dupo aarẹ orileede yii lọdun 2023 di mimọ fun Aarẹ, o lafọbajẹ loun tẹlẹ, asiko si ti to toun fẹẹ jọba wayi.
Ọrọ yii ni Bọde George n fesi si nigba to n ba iweeroyin Punch sọrọ lọjọ Mọnde naa, o ni ọpọ eeyan to kunju oṣuwọn lati jẹ aarẹ orileede yii lo wa nilẹ Yoruba, ṣugbọn Bọla Tinubu ko si lara wọn.
“Awada kẹrikẹri ni erongba Tinubu yii. Ipo aarẹ orileede Naijiria ko si fawọn eeyan bii Bọla Tinubu. Ẹ wo bo ṣe ba ọrọ-aje ati alumọọni ilu Eko jẹ. O yaayan lẹnu pe iru ẹ le tun n loun lalaa lati di aarẹ orileede yii. Ala ọsangangan lo n la, o n tan’ra ẹ jẹ ni.
“Ibi ti ọrọ ipo aarẹ to kan yii maa ja si maa ya Tinubu funra ẹ lẹnu, nigba to ba ri i bawọn to n fọkan tan ṣe maa ja a kulẹ.
“Abuku nla lo maa jẹ fun ilẹ Yoruba, to ba jẹ pe a o ri ẹlomi-in fa kalẹ laduru gbogbo eeyan to wa nilẹ yii, afi iru Tinubu.”
Bakan naa ni Bọde George sọ pe ko yẹ ko jẹ iru ileeṣẹ Aarẹ, ile ijọba apapọ, tawọn eeyan bọwọ fun ni Tinubu yoo ti lọ maa kede erongba rẹ lati dupo aarẹ, o ni ko bọ si i rara.