Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin odi kan, Sunday Alabi, lori ẹsun pe o ṣa ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Sakiru, ẹni tọpọ eeyan mọ si Badoo, pa mọ’nu oko rẹ to wa lagbegbe Ìpólé, eyi to wa nitosi ilu Agbado Ekiti, nijọba ibilẹ Ayekire, nipinlẹ Ekiti.
ALAROYE gbọ pe Alabi ni wọn lo lọ sinu oko Sakiru lọjọ iṣẹlẹ yii lati lọọ ji lara awọn agbado ti ọkunrin ti wọn n pe ni Badoo naa gbin sinu oko rẹ.
Bo ṣe n ji agbado yii ya lọwọ ni Sakiru yọ si i lojiji, to si beere ohun to n wa ninu oko oun lai gba aṣẹ ko too ṣe bẹẹ.
Kaka ki ọkunrin odi yii si bẹbẹ fun idariji, ada lo fa yọ, ko si beṣu-bẹgba rara to fi ṣa Badoo lọrun, to si fẹrẹ ge e ja.
Awọn agbẹ kan to fẹẹ waa ṣiṣẹ ninu oko tiwọn ni wọn ba ọkunrin naa ninu agbara ẹjẹ nilẹ nibi ti Alabi pa a si, ti wọn si lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ni afurasi apaayan naa ti wa lọdọ awọn. O ni ọkunrin naa ti n ran awọn lọwọ ninu iwadii ti awọn n ṣe.