Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni gbọnmi-si i, omi-o-to-o, to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu Onitẹsiwaju, APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, gbọna mi-in yọ pẹlu bi alaga ẹgbẹ ọhun tẹlẹ nipinlẹ Kwara, Hon. Bashir Omolaja Bolarinwa, ṣe wọ Gomina ipinlẹ Yobe to tun jẹ alaga afunnsọ apapọ ẹgbẹ ọhun (CECPC), Mai Mala Buni atawọn akẹgbẹ rẹ, Gomina ipinlẹ Niger ati Gomina ipinlẹ Osun, Sanni Bello ati Gboyega Oyetola, lọ sile-ẹjọ giga ijọba apapọ, to si ni ki kootu fidi ẹ mulẹ bọya o tọna labẹ ofin tabi ko tọna, ki awọn mẹtẹẹta to wa lori apere gẹgẹ bii gomina tun jẹ alaga ati ọkan lara igbimọ CECPC ninu ẹgbẹ APC, gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe gbe e kalẹ.
Ninu iwe ipẹjọ Bolarinwa, o beere pe ofin wo lo yan alaga ati awọn igbimọ CECPC APC, ti igbimọ alakooso ẹgbẹ ko mọ si i gẹgẹ bii iwe ofin ẹgbẹ ọhun ṣe gbe e kalẹ.
Bakan naa ni Bolarinwa tun n beere pe aṣẹ wo ni Buni atawọn igbimọ rẹ ni labẹ ofin ti wọn fi yọ oun nipo gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oselu APC ni Kwara, ti wọn si fi yan Abdullahi Samari bii alaga tuntun, leyii to lodi sofin ẹgbẹ naa.