Alaga ẹgbẹ Labour sun ko ji mọ loru mọju ọjọ idibo aarẹ

Monisọla Saka

Agbọ-sọgba-nu ni iroyin iku alaga ẹgbẹ oṣelu Labour ni agbegbe Karshi, niluu Abuja, Valentine Onuigbo, to ku lojiji. Wọn ni niṣe lo sun ti ko ji mọ.

ALAROYE gbọ pe nidaaji ọjọ Abamẹta, Satide, ti awọn mọlẹbi reti pe o yẹ ki ọkunrin naa ti ji ti wọn ko gburoo rẹ ni wọn lọọ wo o ninu ile. Iyalẹnu lo si jẹ pe oku ọkunrin naa ni wọn ba ninu ile.

A gbọ pe Onuigbo pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu yii mi-in ni wọn jọ n lọ kaakiri, ti wọn n ṣe gbogbo eto to yẹ lati le ri i pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ lasiko eto idibo aarẹ ati ti ileegbimọ aṣofin tt waye lọjọ Abamẹta yii. Wọn si jọ wa nibẹ titi alẹ patapata ti gbogbo wọn fi dagbere funra wọn pe ipade di aarọ ni. Ọkunrin naa si pada sile rẹ, to wọle lọọ sun. Afi bo ṣe di aarọ ọjọ keji ti wọn lọọ wo alaga ẹgbẹ Labour yii ti wọn ni ko ji saye mọ, ibanujẹ nla lo si gba ọkan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa nigba ti wọn gbọ iku ojiji to pa alaga wọn yii.

Awọn kan ni o ṣee ṣe ki ọkunrin naa ti fi ara rẹ ṣe wahala to pọ ju, eyi to fa iku ojiji yii

A gbọ pe wọn ti gbe oku ọkunrin naa lọ si mọṣuari ijọba to wa ni Asokoro.

Leave a Reply