Adewale adeoye
‘Kokooko lara ọta ọga wa le, ko sohun to ṣe alaga ajọ eleto idibo orileede yii, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu rara. Awọn ọta rẹ lo wa nidii iroyin ẹlẹjẹ ọhun ti wọn n gbe kiri pe o ti ku’. Eyi lọrọ to n jade lẹnu alukoro eto iroyin fun ajọ INEC, Rotimi Oyekanmi, lati ta ko iroyin iku alaga ajọ naa tawọn kan n gbe kaakiri ori ayelujara pe alaga ajọ eleto idibo orileede yii ti ku.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun yii, ni iroyin iku Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, gba igboro kan, ti wọn n sọ pe ileewosan ijọba kan nilẹ Gẹẹsi to ti n gba itọju si ailera rẹ kan lo ku si.
Nigba to maa fi di ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun yii, ni Alukoro eto iroyin ajọ ọhun, Rotimi Oyekanmi, bọ sita, to si sọ pe ko soootọ kankan ninu iroyin iku alaga ajọ eleto idibo naa rara. O ni awọn ọta rẹ kan lo wa nidii ọrọ iku naa.
Atẹjade kan to fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘O ti de setiigbọ wa pe awọn kan n gbe iroyin ẹlẹjẹ kan kaakiri ilu pe alaga ajọ eleto idibo orileede yii, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ti ku sileewosan ijọba kan to wa niluu London, lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun yii, eyi ki i ṣoootọ rara, awọn ọbayejẹ ẹda kan lo wa nidii ọrọ iku rẹ. Kokooko lara ọta rẹ le. A n rọ awọn araalu pe ki wọn ma ṣe gba iroyin iku alaga ajọ INEC gbọ rara, ko ṣaisan debi to maa fi lọọ gba itọju nileewosan kankan l’Oke-Okun.
Fun ọdun meji sasiko yii, Yakubu ko de London, nitori ko lohun to fẹẹ lọọ mu nibẹ rara.