Monisọla Saka
Ileewosan nla kan lagbegbe Wrexham, Wales, lorilẹ-ede United Kingdom, ti juwe ile fun nọọsi kan, wọn si tun fofin de e lati ma ṣe ṣiṣẹ gẹgẹ bii nọọsi mọ titi lae.
Eyi waye latari aṣemaṣe ti obinrin naa ṣe pẹlu ọkan ninu awọn alaisan to n tọju.
Obinrin ti wọn pe ni Penelope Williams yii, ni wọn ni oun pẹlu ọkunrin alaisan to n tọju jọ lajọṣepọ nibi aaye igbọkọsi ileewosan naa, nibẹ ni ọkunrin yii si ti gbẹmi-in mi.
Ọkunrin ti wọn ni ijaya ojiji ati aito èémí (heart attack), lo ṣokunfa iku ẹ yii, ni wọn loun pẹlu nọọsi yii ti n bara wọn ṣe erekere lati bii ọdun kan sẹyin. Lẹyin tawọn alaṣẹ ileewosan naa gbọ si i ni wọn le obinrin naa danu lẹnu iṣẹ.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Fox, lorilẹ-ede UK, ṣe sọ, itọju to ni i ṣe pẹlu arun kindinrin (dialysis), ni wọn n fun ọkunrin naa, amọ o ku lalẹ ọjọ toun pẹlu nọọsi ẹni ọdun mejilelogoji (42) naa pade gbẹyin, iyẹn ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun to kọja.
Ẹyin mọto ọkunrin naa tawọn mejeeji ti jọ n bara wọn lajọṣepọ ni igbaaya ti ṣadeede bu ọkunrin naa so, nibẹ lo si pada ba lọ latari airi itọju oju-ẹsẹ.
Ẹbi akọkọ ti wọn da Arabinrin Williams, yatọ si bo ṣe n ni ibalopọ pẹlu alaisan to n tọju ni bi ko ṣe pe mọto ti wọn fi n gbe oku ati alaisan pajawiri (ambulance), ko si ṣeto bi yoo ṣe ri itọju ni kiakia.
Nigba ti wọn kọkọ gbe ọrọ ẹjọ naa kalẹ niwaju igbimọ ẹgbẹ awọn nọọsi atawọn agbẹbi ni aṣiri ti tu pe ọrẹ to tun jẹ alabaaṣiṣẹpọ ẹ ni Penelope kọkọ pe, dipo ọkọ ambulansi. Gbogbo imọran ti ọrẹ rẹ si fun un pe ko wa iranlọwọ lori bi wọn yoo ṣe gbe e deleewosan ni ko ṣe.
Nigba ti ọrọ doju ru, ti ọrẹ ti obinrin nọọsi yii pe sọ fun un ko ranṣẹ si ọkọ to n gbe alaisan pajawiri, ẹkun lo n sun, idaamu to ba a ko si jẹ ko le mọ nnkan to kan ni ṣiṣe mọ.
Nọọsi yii ti kọkọ purọ pe ọkunrin toun n tọju yii lo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ soun lori opo ayelujara Facebook, lati waa tọju oun nitori oun ko gbadun. O ni awọn ko lo ju ọgbọn iṣẹju si iṣẹju marundinlaaadọta lọ lẹyin mọto ọkunrin naa tawọn ti n sọrọ ti nnkan fi fọju pọ.
O ni bo ṣe di pe ọkunrin naa n gbin, to n mi hẹlẹhẹlẹ niyẹn, to si pada gba ibẹ ku.
Nitori pe o fi ọrọ ibaṣepọ aarin oun pẹlu ẹni to mọ pe o ni aisan to lagbara bẹẹ bo, to si tun fi ẹmi ọkunrin naa ta tẹtẹ nitori bi ko ṣe tete beere fun iranlọwọ lati tọju ẹ ni igbimọ ileewosan naa ṣe le e lẹnu iṣẹ, wọn ni adojutini, to fẹẹ fi iṣẹ nọọsi yilẹ ni obinrin naa.