Jọkẹ Amọri
Bi a ṣe n kọ iroyin yii, ilu Mecca, ni orileede Saudi, ni ọkan ninu awọn arẹwa oṣere ilẹ wa nni, Mercy Aigbe, ti gbogbo eeyan mọ si Hajia Minnah wa bayii, ohun naa ti lọ sibẹ lati mu ọkan lara awọn opo ẹsin Islam ṣẹ. Oṣere yii ko da nikan lọ sibẹ o, oun ati ọkọ rẹ, Kazeem Adeoti, ni wọn jọ rin irin-ajo naa.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa yii, ni oṣere yii gbe fọto ti oun ati ọkọ rẹ ya ni papakọ ofurufu, iyẹn lasiko ti wọn n lọ sori Instagraamu rẹ, to si kọ ọ sibẹ pe ‘Haji 2023, Aliamdullilahi’.
Laipẹ yii ni oṣere naa fẹ ọkan ninu awọn makẹta to maa n gbe fiimu jade, Kazeem Adeoti, ti gbogbo eeyan mọ si ADEKAZ. Bo tilẹ jẹ pe Onigbagbọ ni Mercy, ti ọkọ rẹ si jẹ Musulumi. Ṣugbọn ni gẹrẹ ti wọn fẹ rara wọn tan ni oṣere to maa n pera rẹ ni Aya downer ti yii orukọ rẹ pada, to ni oun ko jẹ Mercy mọ, Hajia Minnah ni oun fẹẹ maa jẹ bayii, oun naa si ni ki awọn eeyan maa pe oun.
Ọpo awọn ti wọn gbọ ohun to sọ yii ni wọn n sọ fun un pe ko le maa pe ara rẹ ni Alaaja, nitori ko ti i lọ si Mecca. Loju-ẹsẹ ni oṣere yii si da wọn lohun pe lọdun 2023 yii loun maa lọ si Mecca. Eyi to ti wa si imuṣẹ bayii.
Nibi ti Mery si mu ọrọ ẹsin Islam to ṣẹṣẹ gba yii ni pataki de, oun ati ọkọ rẹ pe awọn eeyan jọ, ti wọn si ṣe waasi ita gbangba fawọn alaawẹ lasiko Ramadan to lọ yii.
Imura ọmọbinrin naa paapaa ti yatọ, nitori Abaya tawọn obinrin Musulumi maa n wọ loriṣiiriṣii loṣere yii naa n wọ bayii, ti yoo si bori dẹdẹ pẹlu.
Ni bayii, oṣere yii ko fẹnu lasan jẹ Hajia Minnah mọ o, oun naa ti wa niluu Mecca bayii, nibi to ti lọọ sọko fasitaani, ti yoo si tun ṣe awọn iṣe laada mi-in, eyi ti yoo sọ ọ di alaaja ni kikun.
Ibikibi tẹ ẹ ba ti ri Mercy Aigbe bayii, ẹ maa ri eyin Mecca lẹnu rẹ, o si di dandan kẹ ẹ fi Alaaja kun orukọ rẹ, nitori oṣere naa ti di alarafa bayii.
Adura ti awọn ololufẹ rẹ n gba foun ati ọkọ rẹ ni pe bi wọn ṣe lọ layọ naa ni wọn maa de layọ atalaafia.