Albert ni kiyawo mu omi ti wọn fi wẹ oku ẹgbọn ẹ ti ko ba mo si iku ẹ

Adewale Adeoye
Awọn alaṣẹ ilu Atani, nijọba ibilẹ Ogbaru, nipinlẹ Anambra, ti foju Ọgbẹni Albert Eligbue, bale-ẹjọ kan to n ri sọrọ fifi iya jeeyan lọna aitọ ati lilo ọmọde nilokulo, ‘Children, Sexual And Gender-Based Violence Court’ to wa lagbegbe Awka, l’Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii. Ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ ni pe ṣe lo fipa mu obinrin opo kan, Abilekọ Patricia Eligbue, pe ko mu diẹ lara omi ti wọn fi wẹ fun ọkọ rẹ, bo ba da a loju pe ko lọwọ ninu iku to pa ọkunrin ti i ṣe ẹgbọn oun yii.
Ọgbẹni Albert to jẹ aburo oloogbe naa nile-ẹjọ fẹsun oriṣii marun-un ọtọọtọ kan, ti wọn si ni ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣe bẹẹ maa jẹ, bi wọn ba yẹ gbogbo iwe ofin wo daadaa, ti wọn si ri i pe o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.
Loju-ẹsẹ ti wọn ti ka awọn ẹsun to gbe e wa si kootu si i lẹsẹ ni Albert ti sọ niwaju adajọ pe oun ko jẹbi.
Adajọ agba ile ẹjọ naa, Onidaajọ Genevieve Osakwe, sọ pe niwọn igba to jẹ pe ki i ṣe ẹsun ọdaran ni wọn fi kan an, oun faaye beeli silẹ Albert pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000), ati oniduuro meji to lorukọ daadaa laarin ilu naa.
Adajọ ni lara awọn ẹni to gbọdọ ṣe oniduuru fun Albert ni ọba alaye tilu Atani, Ọba Onowu, tabi aarẹ ẹgbẹ agba ilu Atani, kawọn mejeeji si mu fọto meji ọtọọtọ atawọn ohun gidi miiran ti wọn le fi da wọn mọ laarin ilu sile ni kootu.
O ni ki wọn ṣi lọọ ju Albert sọgba ẹwọn Awka, titi digba ti yoo fi ri awọn ohun ti yoo fi gba beeli ara rẹ yii mu wa. Lẹyìn eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply