Ale iyawo mi ko rowo ra bẹẹdi, temi ni wọn waa gbe -Tijani

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Muyinatu Tijani lo ni oun fẹẹ kọ ọkọ oun, Abdulramọn Tijani, nitori ẹ lo ṣe pe ẹjọ si kootu kọkọ-kọkọ to n jokoo l’Ake, l’Abẹokuta. Ṣugbọn nigba ti ọkọ kẹnu bọrọ, niṣe lawọn ara kootu n ṣe ‘haa, hin-in’.

Ọmọ meji ni obinrin to n jẹ Muyina yii bi fọkọ ẹ gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ọdun kọkanla ree toun ti fẹ Abdulramọn, ṣugbọn ọdun keji ree tawọn ko ti jọ gbe mọ, to jẹ oun n gbe lọtọ pẹlu awọn ọmọ ni, oun naa loun si n gbọ bukaata wọn.

Obinrin to fẹẹ kọkọ naa ṣalaye pe ọkọ oun ko nifẹẹ oun nigba tawọn jọ n gbe, o ni ko fẹran awọn ọmọ toun bi fun un pẹlu, bẹẹ lo si maa n lu oun nilukuku, to bẹẹ to jẹ niṣe lo pada da ẹru oun sita lọjọ kan tọmọtọmọ.

Awọn iwa yii naa lo ni ko jẹ koun pada sile Abdulramọn mọ lati ọdun keji. O ni ṣugbọn ni bayii, oun fẹẹ kọ ọ silẹ nilana ofin, ko si maa ṣẹtọ to yẹ lori awọn ọmọ ẹ, ko ma da bukaata wọn da oun nikan.

Nigba to n dahun si ọrọ iyawo ẹ yii, Abdulramọn sọ pe oun gan-an ko fẹ Muyinatu mọ, o ni ki loun yoo fi obinrin to ti lọọ loyun falẹ ṣe.

Ọkọ iyawọ yii sọ pe irinkurin pọ lẹsẹ Muyina, o ni nigba tawọn jọ n gbe paapaa, o maa n yan ale ni, oriṣiiriṣii ọkunrin lo n ba a sun.

Nibi to le de, o ni nigba ti iyawo oun fẹẹ kuro nile, niṣe lo ko awọn ẹru oun kan lọ pẹlu bẹẹdi tawọn jọ fi n sun, bẹẹ ile ale rẹ to fẹ lo gbe bẹẹdi naa lọ.

Abdulramọn sọ pe oun mọ ale iyawo oun naa daadaa, o ni Kazeem lo n jẹ. Ọkunrin naa lo ni o gba ile funyawo oun, ṣugbọn ko rowo ra bẹẹdi.

Iyẹn lo ni o fa a ti Muyina fi waa gbe bẹẹdi tawọn jọ fi n sun, o gbe e nigba toun ko si nile, oun ati ale naa si jọ fi n sun, aṣe o ti loyun fun Kazeem niyẹn fi gba ile fun un, airi bẹẹdi sun ni yara ale lo ṣe waa gbe tile ọkọ.

O tẹsiwaju pe latilẹ ni iyawo oun yii ko ti nifẹẹ oun. Ọkunrin yii sọ pe lalẹ ọjọ igbeyawo paapaa, ko fẹẹ gba kawọn ṣe nnkan kan. O ni ẹkun lo fi gbogbo alẹ igbeyawo sun. Boun ba si fọwọ kan an, bii ẹni ti ọkan rẹ ko tilẹ si lọdọ oun rara lo n ṣe.

O ni bawọn ṣe n ba a yi titi niyẹn to fi ko ara ẹ gba ile ale to fi n ṣọkọ bayii lọ.

Abdulramọn ni ọrọ naa ko ba tiẹ ṣee yanju, to ba jẹ pe Iya Muyina n sọrọ sibi tọrọ wa, ti ko maa gbe lẹyin ọmọ rẹ ni. O ni ko sigba toun fẹjọ iyawo oun sun iya rẹ ti iya naa ba a wi ri, afi ko maa gbe lẹyin ẹ, ko maa sọ pe oun ọkọ rẹ loun jẹbi.

Fun idi eyi, ọkọ iyawo ni ki wọn tete yaa tu ajọṣepọ yii ka o, ko si kinni kan toun yoo fi Muyinatu ṣe mọ. Oun naa fara mọ ipinya to n beere yii gidi.

Eeyan yoo ro pe Muyina yoo sọ pe irọ lọkọ oun n pa ni, tabi pe ko si ootọ kan ninu ẹsun to ka soun lẹsẹ, ṣugbọn obinrin naa ko wi kinni kan lati gbeja ara ẹ, niṣe lo dakẹ fẹmu bi ọkọ ṣe rojọ to.

Aarẹ A.O Abimbọla lo gbọ ẹjọ yii, o ni bẹẹ naa kọ loun yoo tu u ka. Ki wọn pada wa si kootu, ọrọ wọn gba apero gidi.

 

Leave a Reply