Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Abilekọ kan, Kafayat Jamiu, ti sọ fun Adajọ Lawal Ajibade ti kootu ibilẹ kan niluu Ilọrin, pe ko tu oun ati ọkunrin ti oun yan lale, ti oun si bimọ fun, Jamiu, ka, o ni ọrọ rẹ ti su oun tori pe bii oro lawọn ṣẹ maa n ja lojoojumọ.
Adajọ beere lọwọ Kafayat pe bawo ni ọkunrin to gbe wa si ile-ẹjọ naa ṣe jẹ si i ati ibaṣepọ to wa laarin wọn? Kafayat ni ọkọ oun ni. Adajọ tun beere pe iru igbeyawo wo ni wọn ṣe, o si dahun pe awọn ko ṣegbeyawo kankan, niṣe lawọn yan ara awọn lale, tawọn si bimọ kan fun ara wọn.
Adajọ ni niwọn igba to ti sọ pe awọn ko ṣe igbeyawo, ti ẹnikẹni ko so wọn pọ, ko si ohun ti ile-ẹjọ fẹẹ tu ka, nitori o tumọ si pe ale ni wọn yan ara wọn, wọn ki i ṣe lọkọ-laya.
Kafaya ni to ba ri bẹẹ, ki adajọ tu ale yiyan tawọn yan ara awọn naa ka, tori pe o ti su oun.
Nigba ti adajọ beere idi ti wọn fi fẹẹ tu ka, Kafayat ni, ‘o ti su mi patapata, gbogbo igba ni a maa n ja’.
Ṣugbọn Jamiu sọ ni tiẹ pe, ‘emi ṣi nifẹẹ rẹ, ohun ti mo n ba a ja si ni pe mo fẹ ko maa lọ sibi iṣẹ ransọ-ransọ to n ṣe, mi o fẹ ko ya ọlẹ.
Adajọ Lawal Ajibade tu ale yiyan naa ka laarin awọn mejeeji, o gba Jamiu nimọran pe to ba fẹẹ fẹ Kafayat loootọ, ko lọ sile wọn lati lọọ tọrọ rẹ lọwọ awọn obi rẹ.