Adewale Adeoye
Ọkan lara awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja, Sẹnetọ Ali Ndume, ti ni oun maa fara mọ ọn pe ki wọn ṣe ofin lati maa pa awọn oloṣelu orileede yii bi wọn ba ji owo ijọba, ṣugbọn ki i ṣe awọn to ba ji owo keekeeke lawujọ wa.
Senatọ Ali Ndume sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun yii, lasiko eto pataki kan lori tẹlifiṣan aladaani kan ti wọn n pe ni ‘Channel TV’.
Ni idahun rẹ si ibeere kan ti atọkun eto naa bi i pe, n jẹ ko yẹ ki wọn ṣofin lati maa pa awọn oloṣelu orileede yii gbogbo ti wọn n ji owo araalu ati owo ijọba nigba gbogbo,
O ni ki i ṣe awọn ti wọn ba ji miliọnu kan Naira tabi biliọnu kan lawujọ wa ni ki wọn maa pa, bi ko ṣe awọn oloṣelu ti wọn ba ji tiriliọnu ni iku tọ si lawujọ wa, nitori pe awọn yẹn gan-an ni ọta ilu ati ti ilọsiwaju orileede Naijiria ni gbogbo ọna.
Ali Ndume sọ pe, ‘Bẹ ẹ ba ni ka foju inu wo ọrọ naa daadaa, iwa ibajẹ awa oloṣelu kere si eyi tawọn araalu n hu, gbogbo ẹnu ni mo fi le sọrọ yii nibikibi, awọn araalu atawọn ololufẹ wa gbogbo ta a fẹẹ tẹ lọrun lo jẹ ka maa ṣiwa-hu lẹkọọkan, ba a ba ji owo ilu ko, a maa lọọ pin in fawọn araalu ti wọn jẹ ọmọlẹyin wọn ti wọn jẹ araalu ni. Bi ẹ ko ba fun wọn lowo ọhun, o daju pe irufẹ oloṣelu bẹẹ ko ni i pada sileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja mọ, ṣugbọn mi o ro pe o yẹ ka maa ji owo ijọba sapo rara. ‘’Ojulowo ọmọ ileegbimọ aṣofin agba ni mi, mi o ni i fi dudu pe funfun fawọn araalu, bi a ba fẹẹ ṣofin pe ki wọn maa pa awọn to ba kowo ijọba jẹ, ma a fara mọ ọn, ṣugbọn ki i ṣe pe ki wọn maa pa awọn to ba ji owo idakọmu rara, idajọ iku ko yẹ fawọn to ba ji miliọnu kan Naira kan tabi biliọnu naira kan lawujọ wa, ṣugbọn wọn le ṣedajọ iku fawọn to ba ji tiriliọnu Naira ati bẹẹ bẹẹ lọ. Gbogbo ara ni mo fi mọ ọn pe ki wọn maa pa awọn to n ta egboogi oloro laarin ilu, nitori pe ọpọ araalu ni wọn n pa sara, wọn n baye awọn ọdọ orileede yii jẹ ni.