Alice wọle tọ ọrẹkunrin ẹ loru, lo ba gun un lọbẹ pa

Mistura Afọlabi

Latari bo ṣe yọbẹ si ọrẹkunrin ẹ lọganjọ oru, to si gun un pa nigba ti wọn n ja, ọdọmọbinrin kan, Alice Mulak, ti n ṣalaye ara ẹ lakolo ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ.

Ẹyin otẹẹli City Rock, niluu Ungwan Gwari, nijọba ibilẹ Karu, nipinlẹ Nasarawa, niṣẹlẹ naa ti waye, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Rahman Nansel, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni iwadii akọkọ tawọn ṣe fihan pe aajin oru lọrọ ọhun ṣẹlẹ, ni nnkan bii aago mẹta aabọ.

Awọn aladuugbo ni wọn tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago pe awọn eeyan wọnyi n ja, nigba ti CSP Musa Babalọla atawọn ọmọọṣẹ ẹ fi maa debẹ, oku ọkunrin naa ni wọn ba, wọn ri ọbẹ ti wọn fi gun un, ọwọ wọn si tẹ afurasi ọdaran to gun un lọbẹ ọhun, ni wọn ba gbe e lọ si teṣan wọn.

Ni bayii, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, CP Adeṣina Ṣoyẹmi, ti ni ki wọn taari afurasi naa sẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Lafia, ki wọn le ṣewadii ijinlẹ lori ọrọ yii.

Lẹyin iwadii ni Alice yoo fara han niwaju adajọ.

Leave a Reply