Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn iran kan (Ọkọmi) ni wọn maa n ki loriki pe “adọkọ loju agbara ki yanrin ma da si i.” Ṣugbọn ni ti Oreke, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bọ laṣiiri, loootọ ni wọn pe ba oun naa laṣepọ lẹgbẹẹ gọta, ṣugbọn iyatọ to wa nibi tiẹ ni pe kinni ọhun ko ti ọkan rẹ wa, wọn fipa ba a laṣepọ nibẹ ni.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, iṣẹ ni wọn ran ọmọdebinrin ẹni ọdun mejila (12) yii to fi kagbako ọkunrin ẹni ọdun marundilogoji (35) ọhun to n jẹ Lukman Azeez, ẹni to deede ki i mọlẹ loju ọna, to si fipa ba a laṣepọ lẹgbẹẹ gọta ni bebe ọna.
Ni nnkan nii aago meje aabọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹdọgbọn (25), oṣu to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye labule kan ti wọn n pe ni Ayetoro-Oke, nitosi ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, nigba ti Lukman lọọ dena de ọmọọlọmọ loju ọna to n gba lọọ jiṣẹ ti wọn ran an, to si ki nnkan bọ ọmọọlọmọ loju ara.
Ariwo ti Oreke fi bọnu lawọn araadugbo naa gbọ ti wọn fi sare lọọ gba a silẹ ko too di pe wọn fa oniṣẹkiṣẹ ọkunrin naa le awọn agbofinro lọwọ.
Lọjọ Aje, Mọnde yii, lawọn ọlọpaa gbe afurasi ọdaran naa lọ si kootu Majisreeti to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan.
Ẹsun ifipa ba ọmọde lo pọ lọna aitọ ni Ripẹtọ Gbemisọla Adedeji to ṣoju awọn ọlọpaa ni kootu fi kan Lukman, o ni, “Ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ ọjọ kẹẹẹdọgbọn, osu kẹwaa, ọdun yii, olujẹjọ yii fipa ba ọmọ aladuugbo rẹ laṣepọ legbẹẹ gọta lasiko to n lọọ ra alubọsa ti iya rẹ ran an.
“Iwadii wa fidi ẹ mulẹ pe bi ọmọ yẹn ṣe fẹẹ pariwo lolujẹjọ sare fọwọ bo o lẹnu, ko too di pe awọn ara adugbo yẹn gba ọmọ yẹn silẹ nibi to ti n ṣe kinni yẹn fun un lọwọ.”
Adajọ kootu naa, Onidaajọ S.H. Adebisi, ko faaye silẹ lati gbọ awijare olujẹjọ naa to fi paṣẹ pe ki wọn fi i pamọ sinu ahamọ ọgba ẹwọn Abolongo to wa niluu Ọyọ, titi ti kootu naa yoo fi ri imọran gba lati ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ naa lori ọna ti wọn yoo gbe ẹjọ naa gba.