Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori ipa takunakun to n ko lati gba gbogbo ilẹ Yorùbá silẹ lọwọ awọn apanijaye Fúlàní, apapọ ẹgbẹ awọn ọdọ Yorùbá, ìyẹn Yoruba Youth Socio-Cultural Association, YYSA, lọọ gbe àmì-ẹyẹ nla kan ka Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo aye mọ̀ si Sunday Igboho mọle nirọlẹ ọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, to kọja.
Ṣugbọn sí iyalẹnu awọn adari ẹgbẹ naa, akínkanjú ọmọ Yorùbà yii kọ àmì-ẹyẹ naa, o ni oun ko ti i ṣàṣeyọrí nipa ominira gbogbo ọmọ Yorùbá tí oun n wá.
ALAROYE gbọ pe eyi kọ nigba akọkọ ti Sunday Ìgbòho yoo kọ àmì-ẹyẹ sí àwọn tó fẹẹ fi imọriri wọn hàn nípa ijijagbara rẹ lọrun.
Ọkan ninu awọn ọmọ ẹyìn Igboho fìdí ẹ mulẹ fakọroyin wa pe “Eyi ki i ṣe igba akọkọ ọga, bẹẹ náà ni wọn kọ amì-ẹyẹ ‘Ogo Ọmọ Yorùbá’ tí àwọn ẹgbẹ kan naa fún wọn lọjọ kẹwàá, oṣù kin-in-ni, ọdun 2021 yii.”
Nigba to n dupẹ fún ìmọ riri ẹgbẹ awọn ọdọ naa lori akitiyan rẹ̀, Sunday Igboho sọ pé “Mi o ti i nilo ami-ẹyẹ bayii. Asiko ti gbogbo wa ni iṣẹ lati ṣe ka tóo lè máa sun oorun àsùn-han-an-run la wa yii, kì í ṣe asiko lati máa kan saara sí mi pé mo ṣiṣẹ takuntakun.
“Nigba ta a ba ṣàṣeyọrí lori iṣẹ ta a dawọ le yii, nigba naa, a le waa máa fúnra wa lami-ẹyẹ ba a bá ṣe fẹ.
“Lọwọlọwọ yii, adua ni mo fẹ ki ẹyin ọdọ ati gbogbo ọmọ Yorùbá máa fi ran mi lọwọ ká lè ṣaṣeyọri lori ominira Yoruba ta a fẹ.
Ààrẹ ẹgbẹ YYSA, Ọgbẹni Habib Ọlálékan Hammed, atawọn eeyan rẹ waa ṣèlérí atilẹyin gbogbo ọdọ Yorùbá fún Sunday Igboho, nigba yoowu to ba nilo wọn.