Ọlawale Ajao, Ibadan
Agbara awọn ajinigbe ti dinku nipinlẹ Ọyọ pẹlu bi ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun ipinlẹ naa, ṣe ja wọ ibuba awọn ajinigbe ninu igbo kijikiji, ti wọn si ko awọn nnkan ija oloro wọn lọ.
Oludari agba awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju lo fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ajọ naa ni Mọniya, n’Ibadan, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Ninu ipade oniroyin ọhun lọga awọn agbofinro yii ti sọ pe aṣeyọri ọhun waye latari awọn iṣẹlẹ ijinigbe kan to n waye lẹnu lọọlọọ yii, paapaa, eyi to waye loju ọna Ibadan si Eko laipẹ yii, eyi to mu ki awọn Amọtẹkun bẹrẹ si i fọ gbogbo aginju igbo ipinlẹ Ọyọ kaakiri lati wa awọn ọbayejẹ eeyan naa kan.
O jọ pe awọn agbesunmọmi paapaa ti gburoo pe awọn agbofinro n wa awọn kiri inu igbo, ni wọn ṣe sa asala fẹmi-in ara wọn lai duro gbe awọn nnkan eelo wọn.
Iyẹn lawọn Amọtẹkun ṣe deede kan baagi nla kan ninu aginju igbo, nigba ti wọn yoo si yẹ ẹ wo, ibọn nla nla ti wọn n pe ni AK47 mẹrin pẹlu ọta ibọn to le ni aadọta (50) lo wa nibẹ.
Bakan naa ni wọn ba aṣọ awọn soja to jẹ toke-tilẹ meji ninu apo ọhun, ati fila awọn ọmọ-ogun oju ofurufu ilẹ yii kan pẹlu igbo ati ọti buruku kan bayii ti wọn n pe ni kolorado.
Gẹgẹ bi Ajagun-fẹyinti Ọlayanju ṣe ṣalaye “Gbogbo wa la mọ bi eto aabo ṣe ri lasiko yii, paapaa lọna Ibadan si Eko. Gomina ba wa sọrọ, o ni ka lọọ ṣe gbogbo ohun ta a ba le ṣe lati ri i pe aabo wa fun awọn eeyan ati dukia wọn.
“A gbe ikọ oniwadii kalẹ lati wa awọn inu igbo kaakiri ipinlẹ yii, koda, a de Eko, awa pẹlu awọn ọlọpaa Eko si jọ forikori lori ba a ṣe le fọ awujọ wa mọ kuro lọwọ awọn ajinigbe atawọn ọdaran gbogbo.
“Lọjọ Jimọ ọsẹ to kọja la gbọ pe wọn ri awọn kan to dihamọra pẹlu ibọn nibi kan nipinlẹ Ọyọ nibi, mo ran awọn eeyan wa lọ sibẹ pẹlu awọn fjilante, wọn ni awọn ko ri eeyan nibẹ ṣugbọn awọn ri ijasa pe awọn eeyan kan n ṣe nnkan kan nibẹ nitori wọn ri awọn ọra omi ninu igbo nibẹ. Mo waa ni ki wọn lọọ tun ibẹ wa daadaa.
Nigba ti wọn waa pada lọ, wọn foonu mi pe awọn ri baagi kan ninu igbo, baagi yẹn si wuwo. Mo ni emi naa ti n bọ. A waa lọọ lugọ de awọn ọdaran to n lo awọn aginju igbo wọnyi fun iṣẹ ibi, a ko ri wọn, a tun wa wọn kaakiri inu igbo, a ko ri wọn.
“Nigba ta a yẹ baagi yẹn wo ka ri i pe ibọn AK 47 mẹrin, ati ọta pẹlu awọn aṣọ ṣọja pẹlu igbo ati ọti ti wọn n pe ni kolorado lo wa ninu baagi yẹn. Igbo ati ọti ti wọn n mu yẹn lo jọ pe o maa n jẹ ki oju wọn ranko ti wọn fi maa n huwa ọdaran”.
O waa gboṣuba fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde fun atilẹyin to n ṣe fun awọn Amọtẹkun lati le pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn ara ipinlẹ naa.
Ninu ọrọ tiẹ, ọga ọlọpaa to ti fẹyinti, CP Fatai Owoṣeni, to jẹ oludamọran fun gomina Makinde lori eto aabo, fi awọn araalu lọkan balẹ lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya.
Ọ ni pẹlu awọn nnkan ija awọn ajinigbe ti awọn Amọtẹkun ti ko yii, ẹru yoo ti maa ba awọn ọdaran to ni wọn paapaa nitori niṣe lo da bii igba ti awọn Amọtẹkun ti gba agbara lọwọ wọn.