Amọtẹkun mu Fẹmi ati babalawo ẹ, ọmọdebinrin kan ni wọn fẹẹ fi ṣogun owo l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ekiti, ti tẹ ọmọdekunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Adeniyi Oluwafẹmi, ati babalawo ẹni ọdun mejilelaaadọta kan, Abdulazeez Ogunsakin, lori ẹsun pe wọn fẹẹ paayan lati fi ṣoogun owo.

Adugbo Ajebandele, l’Ado-Ekiti, lọwọ wọn ti tẹ wọn, nibi ti wọn ti fẹẹ pa ọmọdebinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Godfirst Osigba.

Nigba ti wọn n ṣe afihan wọn, Ọga Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti  Birigedia Joe Kọmọlafẹ, sọ pe ọkan lara awọn ọdaran naa, Adeniyi Oluwafẹmi, lo deede da ọmọdebinrin naa lọna nigba to n lọ sileejọsin, to si gbiyanju lati fi ọbẹ du u lọrun.

O ṣalaye pe bo ṣe gba ọmọdebinrin naa mu lati ẹyin lo bẹrẹ si i kigbe, to si n ja fun ẹmi rẹ, to si n gbiyanju lati gba ọbẹ to fẹẹ fi du u lọrun lọwọ rẹ.

Eyi lo fa a ti ọmọdebinrin yii ṣe fara pa yannayanna, to si n kigbe pe ki gbogbo awọn eeyan adugbo gba oun. Awọn araadugbo yii sare jade, wọn si mu ọdaran naa, lẹyin eyi ni wọn fa a le awọn Amọtẹkun lọwọ.

Nigba tawọn oniroyin n fi ọrọ wa ọdaran naa lẹnu wo, o ni loootọ loun gbiyanju lati fi ọbẹ du ọmọdebinrin naa lọrun lẹyin ti oun gba a mu latẹyin.

O sọ pe Ogunsakin to jẹ babalawo oun lo bẹ oun lọwẹ pe ki oun ba oun wa ẹya ara eeyan lati fi ṣe ètùtù oogun owo.

Nigba to n sọ ohun ti oju rẹ ri, ọmọdebinrin naa, Godfirst Osigba, sọ pe oun n lọ sile-ijọsin nirọlẹ ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni, ti ọdaran naa fi ṣadeede gba ọrun oun mu latẹyin, to si gbiyanju lati fi ọbẹ du ọrun oun.

O ṣalaye pe ọwọ ti oun fi di ọbẹ naa mu lo ge ọmọ ika oun maraarun.

O juwe ọkan lara awọn ọdaran to fẹẹ pa a naa gẹgẹ bii alaadugbo oun nibi toun ti n kọ iṣẹ aranṣọ l’Ado-Ekiti.

Leave a Reply