Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti ni igbesẹ ti awọn fẹẹ maa gbe bayii ni ki awọn maa lu gbogbo maaluu to ba ti ba oko oloko jẹ ta ni gbanjo, ti olowo awọn nnkan ọṣin naa yoo si tun foju bale-ẹjọ.
Alakooso ẹsọ alaabo naa, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lo sọrọ yii ninu ipade kan to ṣe pẹlu ẹgbẹ Miyetti Allah, ẹka tipinlẹ Ondo, awọn agbẹ atawọn ti ọrọ kan lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Adelẹyẹ ni ko si aaye mọ fun awọn Fulani darandaran lati maa sanwo ‘gba ma binu’ fawọn oloko ti wọn ba ba nnkan ọgbin wọn jẹ gẹgẹ bi wọn ti n ṣe latẹyinwa, nitori pe wọn ti ṣi oore-ọfẹ ati anfaani ọhun lo.
O ni ohun to ku ti awọn fẹẹ maa ṣe lati asiko yii lọ ni kì awọn lọ sile-ẹjọ lati gba iwe àṣẹ lilu awọn maaluu tọwọ ba ti tẹ fun biba nnkan oninnkan jẹ ta lowo pọọku, bẹẹ lawọn olootu wọn yoo si tun foju bale-ẹjọ fun ijiya to tọ labẹ ofin.
Owo perete tawọn onimaaluu ọhun n san gẹgẹ bii owo ‘gba ma binu’ lo ni ki i to ida kan lara nnkan ti wọn ba jẹ ninu oko oloko.
O ni ọpọ awọn agbẹ to n ya owo ṣiṣẹ oko lawọn Fulani darandaran naa ti da ni gbeṣe nitori imọtara tiwọn nikan, ọpọ igba lo ni wọn maa n fa awọn iṣu, ẹgẹ ati koko ti awọn ẹni ẹlẹni fowo iyebiye gbin tu fun awọn maaluu wọn jẹ tabi ki wọn ji i ko lọọ ṣe jẹ nínú ile wọn.
Maaluu bii ọtalelugba o din mẹwaa (250) ati awọn darandaran meji lo ni ọwọ awọn tẹ ni Ipogun, Ilaramọkin ati Ọwẹna, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, lẹyin ti wọn ti ba oko to le ni ọgbọn sare jẹ́.
Oloye Adelẹyẹ ni gbogbo aṣoju awọn ti ọrọ kan lawọn ti ba ṣepade lori igbesẹ tuntun naa, ti gbogbo wọn si ti buwọ lu iwe pe awọn fara mọ ọn.