Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Warri, nipinlẹ Delta, ti sọ pe, ọwọ awọn ti tẹ Ọgbẹni Sunday Nyero, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, to jẹ olori ikọ adigunjale kan atawọn ẹlegbẹ rẹ gbogbo ti wọn tun mu ijinigbe mọ iṣẹ wọn, ti wọn si maa n ji awọn eeyan gbe lojuna marosẹ Warri si Sapele.
ALAROYE gbọ pe Sunday to jẹ olori ikọ awọn ọdaran naa ni wọn tun pe ni akọbi gbajumọ pasitọ ijọ Ọlọrun kan to wa lagbegbe naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Bright Edafe, sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n wa Sunday atawọn ọmọọṣẹ rẹ yii latigba diẹ sẹyin, lori bi wọn ṣe maa n yọ awọn olugbe agbegbe Warri ati Sapele lẹnu nigba gbogbo, ko too di pe ọwọ tẹ wọn bayii.
Nigba ti wọn n fọrọ wa Sunday lẹnu wo lo ti jẹwọ pe, ‘Mi o mọ ohun to sun mi de idi iwa ọdaran yii rara, emi ni akọbi baba mi, pasitọ ijọ nla kan laarin ilu ni wọn, inu rẹ ko si le dun rara sohun ti mo ṣe yii, mo ti ba orukọ daadaa rẹ jẹ bayii, iyawo ti baba mi ni pọ, ṣugbọn emi gan-an ni akọbi rẹ, iṣẹ agbẹ onirọba ni mo n ṣe tẹlẹ. Mo bẹrẹ si i jale nitori pe mo ni ogun idile ni, ki i ṣe ifẹ inu mi rara.
‘‘Mi o pari iwe mẹwaa mi nitori pe iyawo meji ni baba mi fẹ sile, baba mi ko gbe pẹlu mama mi, eyi lo fi rọrun fun mi lati maa ṣiwa-hu nigba gbogbo, nigba ti ko sẹni kankan to le maa boju to mi. Loootọ mo ti lọọ ba wọn jale lẹẹmẹrin ọtọọtọ, ṣugbọn ẹẹkan pere la ṣe aṣeyọri ninu iwa ijinigbe, gbogbo igba lo jẹ pe ṣe lawọn ọlọpaa maa n le wa kaakiri inu igbo, eyi ta a ṣe, ta fi ri owo diẹ gba, ni ti obinrin kan bayii to n bọ lati ọja, ṣe la ji i gbe, ta a si n beerẹ owo nla lọwọ rẹ. O ni oun ko lowo lọwọ rara, a gba foonu ọwọ rẹ yẹ wo, ko sowo ninu akanti rẹ loootọ, ṣugbọn a ba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira lọwọ re, a ko gbogbo owo naa, a si fun un ni owo diẹ lati fi wọ mọto pada sile rẹ’’.
Edafe ni lara aṣẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Wale Abass, pa fawọn ni pe kawọn lọ kaakri lati fọwọ ofin mu gbogbo awọn ọdaran ti wọn n da ilu laamu. O fi kun un pe awọn kan ni wọn waa ṣofoofo fawọn ọlọpaa pe Sunday atawọn ọmọọṣẹ rẹ wa nibi kan, tawọn si tara ṣaṣa lọọ fọwọ ofin mu gbogbo wọn pata.
O ni gbara tawọn ba ti pari iwadii awọn nipa awọn ọdaran naa lawọn yoo ti foju wọn bale-ẹjọ, ki wọn le lọọ fimu kata ofin.