Anambra ni Moruf ti fibọn gba mọto, ipinlẹ Ọṣun lọwọ ti tẹ ẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Ọgbẹni Ọladipupọ Mọruf, lori ẹsun ole jija.

Alaroye gbọ pe ọkọ Lexus Jeep 330 ni Moruf fibọn gba lọwọ ẹni to ni in, iyẹn Igwe Odinaka, niluu Obosi, nijọba ibilẹ Guusu Idenmiri, nipinlẹ Anambra lọhun-un.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Kẹhinde Longẹ, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣalaye pe, Moruf yinbọn lu Igwe nikun, lasiko to fẹẹ jale mọto naa lọwọ ẹ.

Bo ṣe gba mọto naa tan lo mori le ọna ipinlẹ Ọṣun, nigba ti awọn agbofinro ipinlẹ Anambra si tọpasẹ ọkọ ọhun, ti wọn ri i pe ọna Ọṣun lo wa, ni wọn ṣe fi i to awọn ẹlẹgbẹ wọn nipinlẹ Ọṣun, leti.

Awọn ọlọpaa ‘A’ Division, niluu Ileṣa, la gbọ pe wọn pada mu Moruf loju ọna Ijẹbu-Jẹṣa pẹlu ọkọ ayẹkẹlẹ naa.

Longẹ ṣalaye pe ni kete tiwadii ba ti pari ni ọkunrin naa yoo foju bale ẹjọ.

Leave a Reply