Ọrọ Aunti Sikira ati ọkọ ẹ ni mo n yanju nigba ti wahala to ṣẹlẹ lọṣẹ to kọja yii ṣẹlẹ. Gbogbo eto ti mo ṣe lo ṣiṣẹ. Iya Walia ti ba mi rin gbogbo irin to ku ti mo fẹ ko rin, Safu naa ti jiṣẹ ti mo ran an. Alaaji ati Iya Dele ko mọ, awọn duro wọn n reti awọn eeyan lati Ageege, wọn n reti awọn Famili Alaaji, wọn o mọ pe wọn o ni i wa. Nigba ti ko sẹni naa to kuku fi lọ mi pe ipade wa nile wa tabi pe awọn kan n bọ, nigba to to asiko lati lọ si ṣọọbu, mo yaa mu gele ati iborun mi, mo n lọ sibi iṣẹ oojọ temi. Safu ti lọ tipẹ ni tiẹ, mo ti ni ko tete maa lọ.
Emi ko mọ bi Alaaji ṣe ri mi pe mo n sọ kalẹ, ẹnu sitẹẹpu nisalẹ ni mo ba a, mo yaa kunlẹ buruburu, ọkọ ẹni lolowo ori ẹni, nigba ti n ko si lọkọ meji, eyi ti mo ni yii naa ni n oo maa tọju. Inu oun naa dun, lo ba n ṣadura fun mi. Nigba ti yoo waa ba gbogbo ọrọ jẹ, lo ni ṣe mo n lọ si ṣọọbu ni, mo ni bẹẹ ni. O ni ṣe n ko mọ pe ipade pataki kan wa nile laaarọ yii ni, mo ni n ko mọ, nigba ti ko sẹni to sọ fun mi. O ni ṣe n o waa ni i duro ni, ni mo ba fọwọ pa a laya, mo ni n ko le duro, awọn kan fẹẹ waa ba mi ni ṣọọbu, gbogbo ohun ti wọn ba sọ nipade, n oo waa gbọ ọ ti mo ba de. Mo yaa jade!
Nigba ti a pada de, n ko ṣe bii ẹni to mọ nnkan kan, mo duro, n ko ri ọkọ mi ko waa fun mi labọ, emi si ti mọ ohun to ṣẹlẹ. Alaaji duro titi ko rẹnikan ni, o pe aago awọn yẹn wọn ko dahun, ọrọ naa ko ye e rara. Nigba tawọn kọọkan yoo fi da a lohun, wọn ni awọn jade lọ ni, pe baba lo bẹ awọn niṣẹ, nitori nnkan pajawiri kan ṣẹlẹ, wọn jọ waa sọ pe awọn yoo fi ipade mi-in si Satide to tun n bọ, pe ki gbogbo wọn peju. Ohun ti ko jẹ ki baba ri nnkan kan waa fun mi labọ ẹ niyẹn, ṣugbọn mo mọ pe ọrọ naa n jo o lara, ibi ti mo fẹẹ ba wọ ọ ni mi o ti i mọ.
Ṣugbọn lalẹ ọjọ naa loun funra ẹ waa ri mi, lo ba ni ka wọ yara, ọrọ wa. Ẹjọ Aunti Sikiria lo waa fi sun mi, o ni ki n gbọ ohun to ṣe, pe oun ti pinnu lati le e lọ. Mo kunlẹ fun un pe ko ni suuru fun mi, pe ko ma ti i le e lọ, ko jẹ ki n wadii ọrọ naa ki n waa fun un lesi, ṣugbọn ko ti mọ pe a maa fi eleyii to ṣe yii fa a leti ni, bo ba tun waa sẹ omi-in lẹyin ẹ, afi ka yaa le e lọ loootọ. Nigba ti mo ba a sọrọ, inu ẹ rọ, ohun ti mo si ri ni pe o fẹran Aunti Sikira, ọkan ẹ ko le e lọ, ṣugbọn o fẹ ki ẹni kan bẹ oun lori ọrọ rẹ, ohun ti mo si ṣe naa niyẹn.
Bi ilẹ ti ṣu to, ko duro lọdọ mi, bo ṣe jade ni mo ni ki Safu wa, mo ni ko pe Aunti Sikira bọ fun mi. N lawọn mejeeji ba de. Mo sọ wabiwọsi ọrọ fun Aunti Sikira, mo si ṣalaye ewu to wa ninu ohun to ṣe yii fun un. Mo ni ko mọ pe gbogbo nnkan ni Alaaji le gba, ṣugbọn to ba di ti ṣina ati irinkurin, Alaaji maa kọ ọ silẹ ni, bẹẹ ni ki i ṣe oun nikan, gbogbo ọkunrin lo n ṣe bẹẹ. Aunti Sikira ko jiyan, koda niṣe lo kunlẹ nigba to gbọ pe awọn famili ko wa mọ nitori ohun ti mo ti ba a ṣe. Loju Safu kuku ni gbogbo ẹ, ọrọ ti kọja itiju tabi igberaga kankan.
Nigba to di ọjọ keji, funra mi ni mo fa a lọwọ, ti mo lọọ mu un ba Alaaji, ni Safu naa ba jade si wa, la ba bẹ baba fun un. Alaaji sọrọ, ṣugbọn aanu ẹ ṣe mi, nitori gbogbo bo ṣe ṣe lọjọ naa, nigba ti ọrọ ba dun un pari lo maa n ṣe bẹẹ. Funra Safu lo yọnda, o ni oun yọnda ọjọ meji gbako ki Alaaji fi maa lọ si ọdọ iyaale oun, nitori oun ko fẹ ohun to maa jẹ ki wọn tun wota mọ. Inu Aunti Sikira dun, niṣe lo so mọ Safu. Bawo ni agbalagba ṣe n fẹran ọkunrin to bẹẹ, nitori kinni! Haa, gbogbo obinrin ko ma jọ emi o. Afi Safu yii ni mo tun ri.
Ba a ṣaa ṣe yanju ọrọ yẹn niyẹn o, ti Mọnde si de ti onikaluku gba ibiiṣẹ ẹ lọ. Emi o mọ pe wahala awọn to n ṣe iwọde SARS ti pọ to bẹẹ, afi igba ti a de ṣọọbu ti a bẹrẹ si i gbọ oriṣiiriṣii. Ohun to n dun mi ni pe Akin wa laarin wọn. O wa nibẹ lati igba to ti bẹrẹ. Mo si pe e ko dahun, mo sọ fun baba ẹ, kaka ki iyẹn pe e, niṣe lo n ki ara ẹ, to ni ọmọ oun niyẹn, baba oun lo fiwa jọ, baba oun Arogunmatidi ọkunrin gbangba afoogun gbangba laya. Ṣe ọrọ ni iru iyẹn, arogun-ma-tidi kọ, arogun-ma-jẹun ni.
Alaaji to jẹ ọmọ Arogunmatidi funra ẹ, bo ba gburoo ibọn, yoo sa lọ ni, o waa ni ọmọ temi lo jọ baba oun, ki lo de ti oun onibaba ko jọ baba ẹ. Sẹki ni mo ranṣẹ si ko ba mi wa a lọ, nigba to si di ọjọ Atalaata to ni oun ko ri i, mo ni ko ma sinmi, n ko fẹ wahala. Afi bo ṣe di ọwọ ọsan ti wọn ni konilegbele ti bẹrẹ. ‘Haa’ ni mo ṣe, nitori mo lọ sọdọ lọọya, emi o si gbọ ikede ọhun ki n too lọ. Igba ti awọn naa n mura pe awọn fẹẹ maa sare lọ sile ki aago mẹrin too lu ni mo beere ohun to de, ni wọn ba sọ fun mi pe konilegbele kan ni. Ere ni mo sa pada de ṣọọbu, ka too raaye de ọhun paapaa, aago marun-un ti n lọọ lu.
Niṣe ni mo kuku ba Safu to to ọja silẹ nibẹ, ẹ palẹ mọ, ẹ palẹ mọ ti mo ṣe, Safu ni ki n ni suuru, emi de niyẹn, o dalẹ ki isede too bẹrẹ, mo ṣaa ni ko palẹmọ, bẹẹ lo n ṣe tikọtikọ, ko si sohun to n ṣe e ju pe ko ti i fẹẹ palẹ mọ lọ. Ibi to ti n ṣe yogẹyọgẹ yii ni a ti gbọ ariwo lojiji, ‘Wọn ti n bọ o, wọn ti de o, wọn ti n bọ o! Iya oloyun to wa lọdọ wa, iyẹn Raṣida, lo kọkọ bẹ sita, ko tiẹ ṣe bii ẹni to loyun, o n sa lọ ni. Ni Abbey naa ba tẹle e, wọn ti lọ. Bẹẹ ni Safu n wa ọna lati tilẹkun, ni ko ba tete ri kọkọrọ, ṣe ẹ ri i nigba ti mo han an lapa bayii, mo n wọ ọ lọ ni. Tipatipa la fi pa ilẹkun de, a o fi kọkọrọ ti i.
Ati dele ki ẹru too maa ba wa, ọja rẹpẹtẹ to wa nibẹ, Safu tun loun pa owo kan, bii aadọjọ ẹgbẹrun naria, o loun kan gbe e si ẹgbẹ tebu lọdọ mi ni. Mo ṣaa n fi i lọkan balẹ pe ohun to ba fẹẹ ṣẹlẹ ko ṣẹlẹ, ẹmi eeyan gun ju ẹmi iṣẹ lọ. Bẹẹ ni wọn si ni a ko gbọdọ jade ni ọjọ keji, Safu fẹẹ lọ, mo kọ fun un. Irọlẹ ọjọ Satide la too dọgbọn lọ. Nigba ti a debẹ, awọn ọmọọta mẹta lo wa nibẹ, wọn duro si ẹnu ọna naa gbagba. Bi wọn ti ri mi ni wọn pariwo, ‘Iyaa wa! Atijẹrin lawa ti wa nibi o, nigba ti a ri i pe ẹ tilẹkun lawa ni ka fi ara wa ṣe sikiọriti, ko dẹ sẹnikan to gbabi kọja!’ Ọkan ninu wọn dahun pe ‘Gbabi kọja kẹ! Nigba ti wọn o fẹẹ ṣoriburuku! Mo kan lanu silẹ mo n wo wọn ni o, ati Safu naa!