Apapọ ẹgbẹ ọdọ ati akẹkọọ bii mẹtadinlọgọta fọwọ si Ọṣinbajo lati dupo aarẹ Naijiria

Jọkẹ Amọri

Ẹgbẹ kan to jẹ apapọ awọn akẹkọọ ati ọdọ ti wọn pe ni ‘National Coalition of Youth and Students, (NACOYS) ti apapọ wọn jẹ ẹgbẹ ọtọọtọ bii mẹtadinlaaadọta lawọn ti fọwọ si i pe ki Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, dije dupo fun aarẹ ilẹ Naijira lọdun 2023.

Alakooso ẹgbẹ naa lapapọ, Barrister Festus Ofume, lo sọrọ yii nigba to n ka ipinnu ti ẹgbẹ naa fẹnu ko si lori ọrọ naa sọ pe ‘‘Fun ọjọ iwaju Naijiria, a gbagbọ tọkantọkan pe Yẹmi Ọṣinbajo to jẹ agbẹjọro agba nilẹ yii nikan lo peregede ju lọ lati jẹ aarẹ ilẹ Naijiria lasiko yii, pataki ju lọ, nitori awọn imọ ati aṣeyọri to ti ni, paapaa ju lọ ifẹ to ni si awọn ọdọ ode iwoyi ati pe ọrọ eto ọrọ aje orileede yii ye e daadaa. Gbogbo awọn nnkan wọnyi lo jẹyọ ninu iwa ati iṣe rẹ lawọn iigba to fi dele gẹgẹ bii Aarẹ orileede yii pẹlu erongba lati ṣiṣẹ lori awọn aṣeyọri ti wọn ti n ṣe bọ tẹlẹ lati bii ọdun meje sẹyin.

‘‘Pẹlu pe oun lo kunju oṣuwọn ju fun ipo aarẹ ilẹ Naijiria, a ṣetan, fun iṣerere awọn ọdọ ode oni ati awọn iran to n bọ, lati ṣiṣẹ fun yiyan Ọjọgbọ Yẹmi Ọṣinbajo gẹgẹ bii aarẹ ilẹ wa lọdun 2023.’’

O fi kun ọrọ rẹ pe, ‘‘nibi ipade apapọ ti a ṣe niluu Abuja lọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni gbogbo wa ti panu pọ fọwọ si Yẹmi Ọṣinbajo gẹgẹ bii oludije wa fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023. A fẹnu ko lori eleyii lẹyin ta a ti ṣe ọpọlọpọ iwadii, ti a si ṣe agbeyẹwo gbogbo awọn ohun to ti ṣe lati bii ọdun meje to ti wa nipo gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ ilẹ wa.

Ki i ṣe pe o kun oju oṣuwọn ju gbogbo awọn ti wọn ti n darukọ pe o fẹẹ dije nikan kọ, oun lo le mu atunṣe to yẹ ba gbogbo awọn iṣoro to n koju wa nilẹ yii bii aibọwọ fofin, airiṣẹ ṣe, ipese iṣẹ fun awọn ọdọ. Bẹẹ ni ko sẹni to le fọwọ rọ akitiyan rẹ lori ọrọ imupadabọ sipo ọrọ aje ilẹ wa sẹyin. Idaniloju wa pe yoo ṣeto anfaani fun awọn ọdọ lati ri iṣẹ ṣe lọna imọ ẹrọ.’’

Awọn ẹgbẹ yii ko sai bẹnu ba bo ṣe ṣe pataki pe ki iṣejọba kuro ni apa Oke-Ọya, ko si wa si apa isalẹ fun imuduro ajọṣe ilẹ wa.

 

Leave a Reply