Faith Adebọla
Ṣe wọn ni bi iya nla ba gbe ni ṣanlẹ, kekere a maa gori ẹni. Bẹẹ lọrọ ri fawọn obi ti wọn ji awọn ọmọ wọn gbe nipinlẹ Kaduna lasiko yii, wọn lawọn ajinigbe naa ti kan si wọn, wọn si ti beere pe ki wọn tete ṣeto lati ko ọpọ ounjẹ ṣọwọ sawọn, lati bọ awọn ọmọ wọn to wa lakata awọn.
Bi wọn ṣe wi, lara nnkan tẹnu n jẹ ti wọn ni kawọn obi naa ko ṣọwọ ni apo irẹsi ilẹ okeere mẹwaa (10), ogun (20) apo irẹsi tiwa-n-tiwa ati ogun (20) apo ẹwa.
Wọn tun beere fun paali maggi mẹwaa, kẹẹgi ororo mẹwaa ati baagi iyọ meji ko gbọdọ gbẹyin ninu ẹru ti wọn fẹẹ ko ranṣẹ si wọn ọhun.
Wọn paṣẹ pe ayafi kawọn obi naa kọkọ ṣeto fun awọn nnkan tawọn beere fun yii, ki ajọsọ too le ṣẹlẹ lori owo itusilẹ tawọn maa gba ki wọn too le ri awọn ọmọ wọn pada laaye.
Tẹ o ba gbagbe, oru ọjọ Iṣẹgun, Wẹsidee mọju Ọjọruu yii, lawọn apamọlẹkun agbebọn naa ya bo ọgba ileewe Bethel Baptist High School, to wa laduugbo Maraban Rido, nijọba ibilẹ Chikum, nipinlẹ Kaduna, ti wọn si ji awọn ọmọleewe mọkandinlọgọfa gbe.
Titi di ba a ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to ri awọn ọmọleewe naa.
Iṣẹlẹ yii wa lara ohun ti Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, fi paṣẹ pe ki wọn ti awọn ileewe mẹtala kan nipinlẹ naa, o lawọn ileewe wọnyi wa lawọn ibi tawọn agbebọn naa ti le tete ṣakọlu si.