Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkan ninu awọn ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku Abilekọ Sidikat Adamọlẹkun ti wọn pa nipakupa mọ inu ile rẹ l’Arigidi Akoko, Mubarak Akadiri, ti jẹwọ ipa to ko lori ọrọ iku iya ẹni ọdun mejilelọgọta ọhun.
Mubarak ninu alaye to ṣe nigba to n fara han nile-ẹjọ Majisireeti tuntun to wa lagbegbe NEPA, niluu Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla yii, ni oun gan-an loun ṣeku pa olukọ-fẹyinti naa nitori ariwo to n pa lasiko ti oun wọle lati ji foonu rẹ lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye.
Nigba ti wọn ni ko waa ṣalaye ohun to ro to fi pa iya arugbo naa ni kootu lo ti sọ pe:
‘‘Gẹgẹ bii iṣe mi, ṣe ni mo tun pada lọ sile wọn lẹyin ti mo ti kọkọ lọ sibẹ lati ba wọn ṣiṣẹ nitori oṣiṣẹ ile wọn ni iya mi i ṣe.
‘‘Bi mo ṣe ji foonu wọn tan ti mo pẹyin da ki n maa sa lọ ni mama di aṣọ mi mu lati ẹyin, mo kọkọ la apoti mọ wọn lori ki wọn le fi mi silẹ, ṣugbọn dipo ki wọn ṣe bẹẹ, ariwo buruku ni wọn n pa, eyi lo jẹ ki n tubọ la apoti naa mọ wọn lori daadaa titi ti wọn fi subu lulẹ, ti wọn ku’’.
Ẹsun ti wọn ka si afurasi naa lẹsẹ nile-ẹjọ ni pe o ṣeku pa Abilekọ Sidikat Adamọlẹkun, nipa lila apoti mọ ọn lori lasiko to fẹẹ ji foonu Samsung rẹ, eyi towo rẹ to ẹgbẹrun mẹrindinlaaadọrin Naira (#66, 000).
Wọn ni iṣẹlẹ yii waye lagbegbe Similoluwa, Arigidi Akoko, ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Ẹsun yii ni ọlọpaa Agbefọba, Simon Wada, ni o ta ko abala okoolelọọọdunrun din ẹyọ kan (319), ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Wada, ninu ẹbẹ rẹ rọ adajọ lati paṣẹ fifi olujẹjọ pamọ sinu ọgba ẹwọn titi digba ti ile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni, ninu ipinnu rẹ gba aba yii wọle, o si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024.