Jamiu Abayọmi
Nitori pe awọn eeyan adugbo rẹ ko pada dibo fun un lẹẹkeji, eyi to mu ko padanu lati ṣoju awọn eeyan agbegbe rẹ, pẹlu ibinu ni ọkunrin oloṣelu kan lorileede Ugandan, Patrick Okumu-Ringa, ṣe lọọ ba gbogbo kanga-dẹrọto n lọ bii mẹwaa to ṣe saduugbo naa jẹ lọsẹ to kọja yii.
O ni awọn eeyan agbegbe toun n ṣoju yii ko mọ riri oun latari bo ṣe lulẹ ninu eto idibo kan to waye niluu naa laipe yii, lo ba ni kawọn eeyan naa maa lọọ wa ọna mi-in ti wọn yoo maa fi romi pọn.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Nebbi Municipality, lọkunrin naa n ṣoju fun, lẹyin to lulẹ ninu eto idibo ile-igbimọ aṣofin ti wọn ṣe ninu oṣu Keje, ọdun 2023 yii, lo ba fibinu ba gbogbo omi ẹrọ adugbo naa jẹ, to si ni alaimoore lawọn toun n ṣoju fun, pẹlu bi wọn ko ṣe fi ibo san oore toun ti ṣe fun wọn lagbegbe naa, o ni afibiṣoloore ati amoore su-ni-i-ṣe ni wọn.
“Awọn eeyan yii o moore rara, ohun ti mo fẹ lọwọ wọn ko ju ibo wọn lọ, lati fi san awọn oore loriṣiiriṣii ti mo ti ṣe fun wọn, mo ti ran ọmọ ọpọlọpọ ninu wọn niwee jade, ṣugbọn sibẹ naa, mi o ṣe nnkan kan ni wọn maa n tẹnu mọ.
“Owo ara mi ni mo n na le awọn ẹrọ omi naa lori, ti mo si maa n ṣe atunṣẹ rẹ nigba gbogbo, kawọn afoore su-ni-i-ṣe yii le ri omi lo, mo si laṣẹ lati ba a jẹ, niwọn igba to jẹ pe ori ilẹ mi lo wa”.
Omi ẹrọ naa ni wọn lo to ọdunrun miliọnu niye owo ilẹ Uganda, to si ti le logun ọdun tawọn araadugbo Nebbi ti n jẹ igbadun rẹ.
Lasiko tawọn oniroyin kan si i lati wadii ọrọ lẹnu rẹ, niṣe ni amugbalẹgbẹẹ rẹ ni ko si nile, o ni ara rẹ ko da.
Awọn olugbe adugbo tọkunrin yii ti huwa ọdaju yii ti fi ẹdun ọkan wọn han latari bi omi to wọn bii imi-eegun laduugbo naa, ti ọkunrin yii si tun waa ba eyi ti wọn n ri mu jẹ bayii. Wọn juwe iwa to hu naa bii iwa ika ati ailaaanu.
Wọn sọ siwaju pe ọkunrin naa ya onimọ tara-ẹni nikan, eyi gan-an lo jẹ kawọn yọ ṣọọki lẹsẹ rẹ to fi lulẹ ninu eto idibo to kọja naa.
Wọn waa ke si ijọba orileede Uganda lati ba wọn da si ọrọ naa, ki wọn si waa bawọn ṣe omi ti ọkunrin naa bajẹ.
.