Ara meriyiiri, ọkunrin yii ṣiṣẹ abẹ to mu ki ẹsẹ rẹ gun si i

Monisọla Saka

Awọn Yoruba ni wọn maa n ṣọ pe beeyan ba roju tan nigba mi-in, yoo maa wa airoju kiri. Eyi gan-an lo ṣe wẹku pẹlu ọkunrin kan, Moses Gibson, to n gbe ni Minneapolis, lorilẹ-ede Amẹrika, ti ko ri ohun to fẹẹ fi owo ṣe mọ, lo ba lọ sọdọ awọn dokita, o ni ko tẹ oun lọrun bi oun ṣe kuru yii, oun fẹẹ ga si i, nitori idi eyi, ki wọn ba oun ṣe e ti ẹsẹ oun yoo fi gun si i. Ṣe ẹni ti yoo ba ga, ẹsẹ rẹ gbọdọ tin-in-rin. Awọn dokita na ko fakoko ṣofo, wọn gbe ọmọkunrin to fẹẹ ga si i ju bi Ọlọrun ṣe da a yii wọnu tiata, wọn ṣiṣẹ abẹ fun un, wọn ṣe fi íńṣì marun-un kun iwọn bo ṣe ga tẹlẹ, n ni Gibson ba di ọmọ-ga.

Alaye ti Gibson ṣe fawọn dokita pe o mu ki oun fẹẹ ṣiṣẹ abẹ naa ni pe agbara kaka loun fi maa n duro ba awọn obinrin sọrọ, nitori iye meji ati itiju to maa n ṣe oun pẹlu iru ara ti Ọlọrun fun oun, ati bi oun ko ṣe ga. Gibson ni latigba toun ti wa lọmọ ọdun mẹẹẹdogun (15), ni ọrọ b’oun ṣe kuru yii ti maa n dun oun lọkan, lẹyin toun ri awọn ọmọkunrin ti awọn jọ jẹ ọjọ ori kan naa ti wọn n ga si i, ṣugbọn toun ko kuro loju kan naa.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Mail ṣe sọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, oniruuru oogun lọkunrin yii ti lo, koda o tun kan sawọn ti wọn n ṣe aajo nilana ibilẹ lori ẹrọ ayelujara, awọn yii ni wọn fi i lọkan balẹ pe awọn yoo ba a ṣe e ti yoo fi ga ju bo ṣe lero lọ, amọ ti gbogbo rẹ ja si pabo.

Lẹyin to gbiyanju gbogbo awọn ọna yii ti nnkan ko lọ bo ṣe ro ni Gibson gba ileewosan lọ lati ṣiṣẹ abẹ ti yoo mu ki ẹsẹ rẹ gun, ko si tibẹ ga si i.

Nigba to n sọrọ lori awọn ilakaka ati akitiyan to ti ṣe lojuna ati le yọ ọrun soke si i, o ni, “Mo ti daamu gan-an ki n baa le ga ju bi mo ṣe wa yii lọ. Koda nigba ti mo wa nileewe girama, inu mi maa n bajẹ pẹlu bi mo ṣe kuru ni’’.

O ni nigba toun tun gbọ nipa ọna abayọ kan ti yoo mu ki ẹsẹ oun gun si i, loun bẹrẹ si i ṣiṣẹ karakara ju tatẹyinwa lọ lati le ribi tu owo jọ fun iṣẹ abẹ naa nigba toun wa nileewe giga.

O ni lẹyin toun gbiyanju lati maa ṣiṣẹ gẹgẹ bii onimọ ẹrọ ayelujara loju ọsan, ati awakọ kabukabu laarin oru, fọdun mẹta gbako, loun lọọ ṣiṣẹ abẹ ti wọn fi fi íńṣì mẹta kun bi oun ṣe ga tẹlẹ naa lọdun 2016. Ọdun meje lẹyin ẹ, iyẹn lọdun 2023 yii, lo loun pada lọọ ṣe ẹlẹẹkeji, nibi ti wọn ti lo nnkan eelo imọ ẹrọ igbalode to maa n mu ki eeyan ga si i fun oun.

Egungun ọrun ẹsẹ ati ibi ìgbaròkó ẹsẹ, mọ ẹyin ati ojugun Gibson, lawọn dokita fọ, ti wọn ti iṣo agberin (magnetic nail) to maa n mu ki ẹya ara gun si i bọ ọ.

Ẹẹmẹta lojumọ ni wọn ni yoo maa lo ohun eelo amáranà yii, lẹyin to ba ya awọn egungun ti wọn fọ ọhun si ẹgbẹẹgbẹ, ni yoo ti awọn nnkan eelo yii bọ inu ẹ.

Leave a Reply