Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti kilọ fun gomina ana, Alhaji Adegboyega Oyetọla, lati ma ṣe darukọ oun si wahala ẹsun obitibiti gbese ti Gomina Ademọla Adeleke fi kan ijọba rẹ.
Arẹgbẹṣọla ṣalaye pe akọwe-owo nipinlẹ Ọṣun ni gbogbo akọsilẹ bi ijọba ọlọdun mẹjọ toun ṣe nipinlẹ Ọṣun ṣe yawo, ati bi wọn ṣe san an pada, oun lo si wa nipo lati ṣalaye ibi ti akanti Ọṣun de duro.
Gomina Adeleke lo sọ fun awọn ori-ade nipinlẹ Ọṣun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe owo to le ni irinwo biliọnu Naira ni gbese tijọba Oyetọla fi silẹ, bẹẹ lo si ya biliọnu mejidinlogun ni kete tiṣejọba rẹ kẹnu bodo loṣu Keje, ọdun yii.
Ṣugbọn Akọwe iroyin fun Oyetọla, Ismail Omipidan, sọ pe irọ funfun balau ni ọrọ ti Adeleke sọ, o ni ki wọn gbe akọsilẹ asiko ti wọn ya awọn owo naa jade, wọn yoo si mọ pe ijọba Arẹgbẹṣọla lo ti Ọṣun sinu agbami gbese.
Ni ti biliọnu mejidinlogun Naira ti wọn sọ, Omipidan ṣalaye pe ijọba apapọ lo fun gbogbo ijọba ipinlẹ lowo naa laarin oṣu Kejila, ọdun 2021, si oṣu Karun-un, ọdun 2022, o ni nibo waa ni Oyetọla ti yawo lẹyin idibo.
Bakan naa ni Kọmiṣanna feto iṣuna fun Oyetọla lasiko iṣejọba rẹ, Bọla Oyebamiji, sọ pe gomina naa ko yawo kankan nibikibi fun odidi ọdun mẹrin iṣejọba rẹ, o ni lati asiko ijọba Arẹgbẹṣọla ni gbese naa ti wa lọrun Ọṣun.
Ṣugbọn atẹjade kan latọdọ Akọwe iroyin fun Arẹgbẹṣọla, Ṣọla Faṣure, sọ pe ọrọ rirun ni Oyebamiji n sọ, o ni aarin Oyetọla ati Adeleke ni wahala naa wa, ki ẹnikankan ma ṣe darukọ Arẹgbẹṣọla si i rara.
O ji loootọ nijọba oun ya awọn owo kan nigba naa, ṣugbọn oun ti san meji to pọ ju ninu awọn owo naa to jẹ owo Sukkuk, nigba ti awọn yooku jẹ eyi ti awọn gba lọwọ ijọba apapọ, ti idapada rẹ si ni asiko to gun pupọ.
O ni gbogbo ẹleyii ni akọwe-owo funjọba ipinlẹ Ọṣun mọ nipa rẹ yekeyeke, nitori oun lo gbe awọn gbese naa jade fun gomina tuntun, ko si nnkan to kan oun (Arẹgbẹṣọla) nibẹ rara.
O sọ siwaju pe, “Ṣẹ Arẹgbẹṣọla lo sọ pe ko lọọ ya biliọnu mejidinlogun Naira lẹyin to fidi-rẹmi ninu idibo? Awọn ni wọn da wahala sọrun ara wọn. To ba jẹ pe wọn ti ṣagbekalẹ igbimọ ti yoo ṣeto gbigbe agbara le ijọba tuntun lọwọ nigba naa, irọrun ni gbogbo nnkan iba ba de.
“Ṣugbọn dipo eleyii, koto wahala lo n gbẹ silẹ funjọba to n bọ, to si n nawo ninakunaa. Ki lo fi biliọnu mejidinlogun Naira ṣe? Tijọba tuntun yii ba gbe ọrọ yii lọ sọdọ ajọ EFCC, wahala maa wa fun ijọba Oyetọla”.