Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ Ọranmiyan kaakiri agbaye, Ọranmiyan Group Worldwide, Ọmọọba Felix Awofisayọ, ti ke si Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, lati jawọ ninu awọn iwa to le da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru.
Ọmọọba Awofisayọ, ẹni to jẹ ọkan pataki lara awọn aṣaaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, bu ẹnu atẹ lu bi awọn oṣiṣẹ alaabo ati awọn ‘janduuku’ ti wọn tẹle Arẹgbẹṣọla wọ ilu Oṣogbo lọjọ Aje, Mọnde, ṣe n yinbọn lakọlakọ, ti awọn araalu si n sa kijokijo kaakiri.
Ninu atẹjade kan to fi ranṣẹ si ALAROYE lo ti woye pe iru iwa bẹẹ ko bojumu rara, gbogbo olufẹ alaafia lorileede yii lo si yẹ ki wọn gboju aagan si iṣẹlẹ naa.
Awofisayọ sọ siwaju pe, “Emi o mọ nnkan ti Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla fẹẹ gba ninu wahala naa ti ọkan lara awọn ọta ibọn ti awọn oṣiṣẹ alaabo rẹ atawọn tọọgi ti wọn tẹle e yẹn ba lọọ ba ẹni to n rin lọ jẹẹjẹ lẹgbẹẹ titi.”
Baba yii parọwa si Arẹgbẹṣọla lati kilọ fun awọn oṣiṣẹ alaabo ati awọn janduku ti wọn n tẹle e, ki wọn jẹ ki awọn araalu fi ibalẹ ọkan jẹgbadun alaafia to wa nipinlẹ Ọṣun.
O beere lọwọ Arẹgbẹṣọla boya ẹnikẹni le dan iru nnkan to dan wo l’Oṣogbo lọjọ Aje wo lasiko to fi jẹ gomina nipinlẹ Ọṣun lai jiya rẹ.
“Nigba ti Arẹgbẹṣọla jẹ gomina nipinlẹ yii, ko sẹni to le sọ pe oun yoo maa wọ kaakiri loju titi fun ipolongo oṣelu lai jiyan rẹ niṣu.”
Awofisayọ gba gomina ana niyanju lati dẹkun dida ipinya silẹ ninu ẹgbẹ APC. Bakan naa lo gba Gomina Oyetọla niyanju lati ma ṣe faaye gba ihalẹ awọn ti wọn ko fẹran iṣejọba rẹ lati di i lọwọ rara.
O ke si awọn araalu lati ma ṣe bẹru, ki wọn maa ṣiṣẹ wọn lọ, pẹlu ileri pe ijọba ko ni i fọwọ lẹran wo ẹnikẹni to ba pinnu lati da wahala silẹ nipinlẹ Ọṣun.