Monisọla Saka
Minisita fọrọ abẹle nilẹ wa, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti ki aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ku oriire lori ijawe olubori ẹ, ninu eto idibo aarẹ oṣu Keji, ọdun yii.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, kede gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri ọhun gẹgẹ bii ẹni to ni ibo to pọ ju lọ, ti yoo si gba eto iṣakoso orilẹ-ede yii lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari.
O ni, “Mo dara pọ mọ awọn aṣaaju ẹgbẹ wa, lati ori Aarẹ Muhammadu Buhari, Igbakeji Aarẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, alaga apapọ ẹgbẹ wa, awọn eekan ninu awọn oloye ẹgbẹ, awọn igbimọ eleto ipolongo ibo, awọn adari yooku jake-jado orilẹ-ede Naijiria atawọn afẹnifẹre gbogbo, lati ki aarẹ wa tuntun, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Kashim Shettima, ti i ṣe igbakeji ẹ ku oriire ijawe olubori wọn ninu eto idibo to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
Ninu atẹjade to fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Arẹgbẹṣọla ti gbe gbogbo ede aiyede to wa laarin wọn ti sẹgbẹẹ kan, to si ba Jagaban dawọọ idunnu oriire ijawe olubori ẹ. Ninu iṣẹ ikini ku oriire ẹ yii lo ti tọka sawọn ọjọ ti ojo ti n pa igun Tinubu bọ, ko too di ẹni to lẹnu lọrọ, ati apaṣẹ nipinlẹ Eko.
Atẹjade to pe akọle rẹ ni “Jagaban: Iṣẹ de” yii, lo ti mẹnu ba awọn ilakaka Tinubu latẹyin wa, lati aye ipo sẹnetọ ati bo ṣe jawe olubori, ọrọ June 12, wahala NADECO, bi wọn ṣe gbe agbara wọ apa Iwọ Oorun ilẹ Naijiria, bo ṣe di gomina nipinlẹ Eko atawọn aṣeyọri mi-in lọlọkan-o-jọkan.
Arẹgbẹṣọla waa gbadura fun Tinubu pe oriire to wọle de yii yoo so eeso rere, yoo si jẹ itẹsiwaju gbogbo awọn iṣẹ rere ati idagbasoke ti eto iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari n ba bọ.
Bakan naa ni Arẹgbẹṣọla tun rọ Tinubu lati ri i daju pe orilẹ-ede Naijiria atawọn eeyan ni imọlara ijọba tuntun yii, ko se iṣẹ ẹ gẹgẹ bo ṣe ti n ba a bọ latẹyin wa, ki ilẹ Naijiria le wa niwaju, gẹgẹ bi wọn ṣe jẹ ọba ni ilẹ Afrika tẹlẹ.
O waa gba a laduura pe Ọlọrun yoo fun un ni alaafia ati ọgbọn ti yoo nilo lati ṣe aṣeyọri ninu ipo to ṣẹṣẹ tẹwọ gba yii.
Arẹgbẹṣọla ti i ṣe jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, to si tun ti figba kan jẹ kọmiṣanna fọrọ iṣẹ nipinlẹ Eko lasiko ti Tinubu n ṣe gomina, loun ati Tinubu ti i ṣe ọga ẹ yii ti di ọsan ati oru lati bii ọdun marun-un sẹyin. Sugbọn ọmkunrin ọmọ ibi ilu Ileṣa naa gbe gbogbo eleyii ti, o si ki ọga rẹ atijọ naa ku oriire.