Arẹwa obinrin kan gbẹmi ara rẹ l’Ekoo

Monisọla Saka
Obinrin oluṣiro owo kan, Fọlakẹ Abiọla, ti gbẹmi ara ẹ ninu ile ẹ to wa laduugbo Abayọmi Kokukọ Close, Osapa London, lagbegbe Lekki, nipinlẹ Eko lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.

ALAROYE gbọ pe ile ni obinrin ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun wa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ ta a lo tan yii ti wọn fi ni o gbe oogun ẹfọn olomi ti wọn n pe ni ‘Sniper’ mu.
Ko pẹ lẹyin igba naa ni wọn sọ pe o dakẹ, gẹgẹ bi awọn ẹbi, ara, ọrẹ atawọn ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ba a nilẹẹlẹ ninu ile ẹ ti ko le mira mọ.
Alabaaṣiṣẹpọ oloogbe ti ko darukọ ara ẹ ṣalaye pe Abiọla ti wa ninu ironu ati ibanujẹ ọkan tawọn oloyinbo n pe ni ‘depression’ latọjọ pipẹ, ati pe iroyin iku ẹ yii ba awọn lẹru gidi.
Yatọ si ohun tawọn kan n sọ pe obinrin naa para ẹ nitori dida to maa n da wa, ti ko lọkọ ati aibimọ rẹ, alabaaṣiṣẹpọ ẹ yii ni awọn tawọn jọ n ṣiṣẹ pọ mọ pe o ti figba kan wa ninu ifẹ ri, ati wi pe ọrọ ironu yii naa lo maa n jẹ ko fopin si pupọ awọn ajọṣepọ oun atawọn ololufẹ ẹ ọhun.
“O ti n wọya ija pẹlu ironu fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin, bẹẹ ni iku ẹ o ni nnkan kan an ṣe pẹlu dida to maa n da wa, ailọkọ tabi ainibalopọ pẹlu ọkunrin. Ni nnkan bii ọdun meje sẹyin, mo mọ pe o pade ololufẹ bii ẹẹmeji ọtọọtọ.

“Funra ẹ lo fopin si awọn ajọṣepọ naa nitori ọrọ ironu yii naa, o loun o ṣetan lati tun mu ẹlomi-in wọnu aye oun nigba toun funra oun gan-an o ti i le da ara oun tọju na.
Ironu gidi ati aidunnu ọkan lo n ba a finra, ṣugbọn awọn eeyan ti ko mọ ohun to n jo o labẹ aṣọ n sọ radarada ti ko jọ mọ ohun to ṣẹlẹ rara lori ẹrọ ayelujara.
“Agba oluṣiro owo ni nileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ Glo, a si jọ n ṣiṣẹ ni. Funra ẹ lo gbẹmi ara rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, awọn eniyan ẹ ti sin oku ẹ, nitori pe oun nikan lo n ṣe ẹsin ọmọlẹyin Kristi ninu ẹbi wọn”.
Alabaaṣiṣẹpọ Biọla yii ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bii angẹli, ẹni to mọṣẹ ẹ dunju, eeyan to nifẹẹ Kristi dọkan, ati afunni-ma-wo-ibẹ, o fi kun un pe, o ti tẹnumọ ọn pe oun fẹẹ fopin si gbogbo ẹ ko too waa pada di pe o gbẹmi ara ẹ.
“Lorilẹ-ede Naijiria wa yii, a ki i ka ọrọ ilera to jẹ mọ ọpọlọ si, ọpọlọpọ eeyan lo gbe ẹwu ẹdun ọkan, ibanujẹ ati ironu wọ, bẹẹ, ko pọn dandan ko jẹ pe kinni kan lo ṣokunfa rẹ”.
A gbọ pe laipẹ yii larẹwa obinrin naa ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlaaadọta laye.
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ pe arabinrin ọhun lo gbẹmi ara rẹ. O ṣalaye pe ni kete ti wọn fọrọ naa to ọga ọlọpaa agbegbe ọhun leti ni wọn ti de ile oloogbe, ṣugbọn oku rẹ lawọn agbofinro ba nilẹ.
O ni awọn agbofinro ba ike oogun ẹfọn olomi ti wọn kọ ‘Sniper’ si lara.

Leave a Reply