Faith Adebọla, Eko
Ẹka eto ilera tijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn olukọ marun-un nileewe sẹkọndiri kan ati akẹkọọ meji ni ẹri ti fihan pe wọn lugbadi arun korona bi wọn ṣe bẹrẹ saa ikẹkọọ pada yii.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii ni atẹjade kan ti kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, buwọ lu sọ ọrọ yii di mimọ.
Dokita Abayọmi ṣalaye pe ayẹwo ti ẹka eto ilera to n lọ kaakiri awọn ileewe ṣe lọjọ keji oṣu kọkanla yii lo ti kọkọ gbe e jade pe tiṣa obinrin kan to n ṣiṣẹ ninu ọkan lara awọn ileewe sẹkọndiri to jẹ tijọba ipinlẹ Eko ti lugbadi arun aṣekupani ọhun, loju ẹsẹ si ni wọn ti mu un lọ sibudo iyasọtọ, nibi to ti n gba itọju.
Lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ si i tọpasẹ awọn olukọ ati akẹkọọ to ṣee ṣe ki wọn ti ni ajọṣe kan pẹlu tiṣa ọhun, ko si ju ọjọ meji si mẹta lẹyin naa lọ ti ayẹwo fi gbe e jade pe awọn tiṣa ẹlẹgbẹ rẹ mẹrin ti lugbadi korona, bẹẹ lawọn ọmọleewe meji ti fara kaaṣe pẹlu.
Abayọmi ni awọn olukọ ati ọmọleewe wọnyi dubulẹ aisan gẹrẹ ti aisan naa ti wa lara wọn, bo tilẹ jẹ pe ileewe ọhun tete pese itọju pajawiri fun wọn, ẹyin naa ni ayẹwo waa fi aisan to n ṣe wọn han pe korona ni.
O sọ siwaju si i pe awọn ti bẹrẹ si i kan si awọn obi ati alagbatọ awọn akẹkọọ to ku nileewe ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun, lati wa lojufo si ilera awọn ọmọ wọn, ki wọn si tete ke gbajare ti wọn ba kẹẹfin ami arun korona eyikeyii.